ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 9:23-29

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 9:23-29 YCE

Bí ọjọ́ tí ń gorí ọjọ́ àwọn Juu gbèrò pọ̀ bí wọn yóo ti ṣe pa á. Ṣugbọn Saulu gbọ́ nípa ète wọn. Wọ́n ń ṣọ́ àwọn ẹnu odi ìlú tọ̀sán-tòru kí wọ́n baà lè pa á. Ṣugbọn ní alẹ́ ọjọ́ kan, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbé e sinu apẹ̀rẹ̀, wọ́n sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ láti orí odi ìlú. Nígbà tí Saulu dé Jerusalẹmu, ó fẹ́ darapọ̀ mọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu. Ṣugbọn ẹ̀rù rẹ̀ ń bà wọ́n; wọn kò gbàgbọ́ pé ó ti di ọmọ-ẹ̀yìn Jesu. Ṣugbọn Banaba mú un lọ sọ́dọ̀ àwọn aposteli, ó ròyìn fún wọn bí ó ti rí Oluwa lọ́nà, bí Oluwa ti bá a sọ̀rọ̀, ati bí ó ti fi ìgboyà waasu lórúkọ Jesu ní Damasku. Ó bá ń bá wọn gbé ní Jerusalẹmu, ó ń wọlé, ó ń jáde, ó ń fi ìgboyà waasu lórúkọ Oluwa, ó ń bá àwọn Juu tí ó ń sọ èdè Giriki jiyàn. Ṣugbọn wọ́n gbèrò láti pa á.