Iṣe Apo 18:1-3 - Compare All Versions

Iṣe Apo 18:1-3 YBCV (Bibeli Mimọ)

LẸHIN nkan wọnyi, Paulu jade kuro ni Ateni, o si lọ si Korinti; O si ri Ju kan ti a npè ni Akuila, ti a bí ni Pontu, ti o ti Itali de nilọ̃lọ̃, pẹlu Priskilla aya rẹ̀; nitoriti Klaudiu paṣẹ pe, ki gbogbo awọn Ju ki o jade kuro ni Romu: o si tọ̀ wọn wá. Ati itori ti iṣe oniṣẹ ọnà kanna, o ba wọn joko, o si nṣiṣẹ: nitori agọ́ pipa ni iṣẹ ọnà wọn.

Iṣe Apo 18:1-3 YCE (Yoruba Bible)

Lẹ́yìn èyí, Paulu kúrò ní Atẹni, ó lọ sí Kọrinti. Ó rí Juu kan níbẹ̀, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Akuila, ará Pọntu. Òun ati Pirisila iyawo rẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ ti ilẹ̀ Itali dé ni, nítorí ọba Kilaudiu pàṣẹ pé kí gbogbo àwọn Juu kúrò ní ìlú Romu. Paulu bá lọ sọ́dọ̀ wọn. Nítorí pé iṣẹ́ kan náà ni wọ́n ń ṣe, Paulu lọ wọ̀ lọ́dọ̀ wọn, ó sì ń ṣiṣẹ́. Iṣẹ́ ọnà awọ tí wọ́n fi ń ṣe àgọ́ ni wọ́n ń ṣe.

Iṣe Apo 18:1-3 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Paulu jáde kúrò ni Ateni lọ sí Kọrinti. Ó sì rí Júù kan tí a ń pè ní Akuila, tí a bí ni Pọntu, tí ó ti Itali dé ní lọ́ọ́lọ́ọ́, pẹ̀lú Priskilla aya rẹ̀; nítorí tí Kilaudiu pàṣẹ pé, kí gbogbo àwọn Júù jáde kúrò ní Romu. Ó sì tọ̀ wọ́n lọ láti rí wọn. Nítorí tí òun náà jẹ́ oníṣẹ̀-ọwọ́ kan náà, ó bá wọn jókòó, ó sì ń ṣiṣẹ́: nítorí àgọ́ pípa ni iṣẹ́ ọwọ́ wọn.