Iṣe Apo 18:1-3
Iṣe Apo 18:1-3 YBCV
LẸHIN nkan wọnyi, Paulu jade kuro ni Ateni, o si lọ si Korinti; O si ri Ju kan ti a npè ni Akuila, ti a bí ni Pontu, ti o ti Itali de nilọ̃lọ̃, pẹlu Priskilla aya rẹ̀; nitoriti Klaudiu paṣẹ pe, ki gbogbo awọn Ju ki o jade kuro ni Romu: o si tọ̀ wọn wá. Ati itori ti iṣe oniṣẹ ọnà kanna, o ba wọn joko, o si nṣiṣẹ: nitori agọ́ pipa ni iṣẹ ọnà wọn.

