II. Sam 7:1-5 - Compare All Versions

II. Sam 7:1-5 YBCV (Bibeli Mimọ)

O si ṣe, nigbati ọba si joko ni ile rẹ̀, ti Oluwa si fun u ni isimi yika kiri kuro lọwọ gbogbo awọn ọta rẹ̀. Ọba si wi fun Natani woli pe, Sa wõ, emi ngbe inu ile ti a fi kedari kọ, ṣugbọn apoti-ẹri Ọlọrun ngbe inu ibi ti a fi aṣọ ke. Natani si wi fun ọba pe, Lọ, ki o si ṣe gbogbo eyi ti o wà li ọkàn rẹ, nitoripe Oluwa wà pẹlu rẹ. O si ṣe li oru na, ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Natani wá, pe, Lọ, sọ fun iranṣẹ mi, fun Dafidi, pe, Bayi li Oluwa wi, iwọ o ha kọ ile fun mi ti emi o gbe?

II. Sam 7:1-5 YCE (Yoruba Bible)

Lẹ́yìn tí Dafidi ọba ti bẹ̀rẹ̀ sí gbé inú ààfin rẹ̀, tí OLUWA ti fi ọkàn rẹ̀ balẹ̀, tí ó sì dáàbò bò ó lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀, ọba wí fún Natani wolii pé, “Èmi ń gbé inú ààfin tí wọ́n fi igi kedari kọ́, ṣugbọn inú àgọ́ ni àpótí ẹ̀rí OLUWA wà!” Natani dá a lóhùn pé, “Ṣe ohunkohun tí ó bá wà ní ọkàn rẹ, nítorí pé OLUWA wà pẹlu rẹ.” Ṣugbọn ní òru ọjọ́ náà, OLUWA wí fún Natani pé, “Lọ sọ fún Dafidi iranṣẹ mi, pé, báyìí ni OLUWA wí, ‘Ṣé o fẹ́ kọ́ ilé fún mi láti máa gbé ni?

II. Sam 7:1-5 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

Ó sì ṣe, nígbà tí ọba ń gbé ní ilé rẹ̀, tí OLúWA sì fún un ní ìsinmi yíkákiri kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀. Ọba sì wí fún Natani wòlíì pé, “Sá wò ó, èmi ń gbé inú ilẹ̀ tí a fi kedari kọ́, ṣùgbọ́n àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run ń gbé inú ibi tí a fi aṣọ gé.” Natani sì wí fún ọba pé, “Lọ, kí o sì ṣe gbogbo èyí tí ó wà ní ọkàn rẹ, nítorí pé OLúWA wà pẹ̀lú rẹ.” Ó sì ṣe ní òru náà, ọ̀rọ̀ OLúWA tọ Natani wá pé, “Lọ, sọ fún ìránṣẹ́ mi, fún Dafidi pé, ‘Báyìí ni OLúWA wí, ìwọ ó ha kọ́ ilé fún mi tí èmi yóò gbé.