II. Sam 1:17-27
II. Sam 1:17-27 Bibeli Mimọ (YBCV)
Dafidi si fi orin ọ̀fọ yi ṣọ̀fọ̀ lori Saulu ati lori Jonatani ọmọ rẹ̀: O si pa aṣẹ lati kọ́ awọn ọmọ Juda ni ilò ọrun: wõ, a ti kọ ọ sinu iwe Jaṣeri. Ẹwà rẹ Israeli li a pa li oke giga rẹ: wò bi awọn alagbara ti ṣubu! Ẹ máṣe sọ ọ ni Gati, ẹ má si ṣe kokiki rẹ̀ ni igboro Aṣkeloni; ki awọn ọmọbinrin Filistini ki o má ba yọ̀, ki ọmọbinrin awọn alaikọla ki o má ba yọ̀. Ẹnyin oke Gilboa, ki ìri ki o má si, ati ki ojò ki o má rọ̀ si nyin, ki ẹ má si ni oko ọrẹ ẹbọ: nitori nibẹ li a gbe sọ asà awọn alagbara nu, asà Saulu, bi ẹnipe a ko fi ororo yàn a. Ọrun Jonatani ki ipada, ati idà Saulu ki ipada lasan lai kan ẹjẹ awọn ti a pa, ati ọra awọn alagbara. Saulu ati Jonatani ni ifẹni si ara wọn, nwọn si dùn li ọjọ aiye wọn, ati ni ikú wọn, nwọn kò ya ara wọn: nwọn yara ju idì lọ, nwọn si li agbara ju kiniun lọ. Ẹnyin ọmọbinrin Israeli, ẹ sọkun lori Saulu, ti o fi aṣọ òdodó ati ohun ọṣọ́ wọ̀ nyin, ti o fi ohun ọṣọ́ wura si ara aṣọ nyin. Wo bi awọn alagbara ti ṣubu larin ogun! A Jonatani! iwọ ti a pa li oke giga rẹ! Wahala ba mi nitori rẹ, Jonatani, arakunrin mi: didùn jọjọ ni iwọ jẹ fun mi: ifẹ rẹ si mi jasi iyanu, o jù ifẹ obinrin lọ. Wo bi awọn alagbara ti ṣubu, ati bi ohun ija ti ṣegbe!
II. Sam 1:17-27 Yoruba Bible (YCE)
Dafidi bá kọ orin arò fún Saulu, ati Jonatani, ọmọ rẹ̀, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n kọ́ àwọn eniyan Juda ní orin náà. (Àkọsílẹ̀ rẹ̀ wà ninu Ìwé Jaṣari.) Orin arò náà lọ báyìí: “A! Israẹli, wọ́n ti pa àwọn tí o fi ń ṣògo lórí àwọn òkè rẹ! Ẹ wo bí àwọn akikanju tí ń ṣubú! Ẹ má ṣe sọ nípa rẹ̀ ní Gati, ẹ má ṣe ròyìn rẹ̀ ní ìgboro Aṣikeloni; kí inú àwọn obinrin Filistini má baà dùn, kí àwọn ọmọbinrin àwọn aláìkọlà má baà máa yọ̀. “Ẹ̀yin òkè Giliboa, kí òjò má ṣe rọ̀ le yín lórí, bẹ́ẹ̀ ni kí ìrì má ṣe sẹ̀ sórí yín, kí èso kan má so mọ́ ní gbogbo orí òkè Giliboa, nítorí pé, ibẹ̀ ni apata àwọn akikanju ti dípẹtà; a kò sì fi òróró kun apata Saulu mọ́. Ọrun Jonatani kì í pada lásán, bẹ́ẹ̀ ni idà Saulu kì í pada, láì fi ẹnu kan ẹ̀jẹ̀ àwọn tí ó pa, ati ọ̀rá àwọn akikanju. “Saulu ati Jonatani, àyànfẹ́ ati eniyan rere, wọn kì í ya ara wọn nígbà ayé wọn, nígbà tí ikú sì dé, wọn kò ya ara wọn. Wọ́n yára ju àṣá lọ, wọ́n sì lágbára ju kinniun lọ. “Ẹ̀yin obinrin Israẹli, ẹ sọkún nítorí Saulu, ẹni tí ó ro yín ní aṣọ elése àlùkò, tí ó sì fi ohun ọ̀ṣọ́ wúrà ṣe yín lọ́ṣọ̀ọ́. “Ẹ wo bí àwọn akikanju tí ń ṣubú lójú ogun! Jonatani ti ṣubú lulẹ̀, wọ́n ti pa á lórí òkè. “Mò ń ṣe ìdárò rẹ, Jonatani arakunrin mi; o ṣọ̀wọ́n fún mi lọpọlọpọ. Ìfẹ́ tí o ní sí mi, kò ṣe é fi ẹnu sọ, ó ju ìfẹ́ obinrin lọ. “Ẹ wo bí àwọn akikanju tí ń ṣubú, tí àwọn ohun ìjà ogun sì ń ṣègbé!”
II. Sam 1:17-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Dafidi sì fi orin ọ̀fọ̀ yìí ṣọ̀fọ̀ lórí Saulu àti lórí Jonatani ọmọ rẹ̀, Ó sì pàṣẹ pé kí a kọ́ àwọn ọkùnrin Juda ní orin arò yìí tí ó jẹ́ ti ọrun (a kọ ọ́ sí inú ìwé Jaṣari): “Ògo rẹ, Israẹli ni a pa ní òkè gíga rẹ. Wò bí àwọn alágbára ṣe ń ṣubú! “Ẹ má ṣe sọ ọ́ ní Gati, ẹ má ṣe kéde rẹ̀ ní òpópónà Aṣkeloni, kí àwọn ọmọbìnrin Filistini má bá à yọ̀, kí àwọn ọmọbìnrin aláìkọlà má ba à dunnú. “Ẹ̀yin òkè Gilboa, kí ẹ̀yin kí ó má ṣe rí ìrì tàbí òjò, tàbí oko tí ó mú èso ọrẹ wá. Nítorí ibẹ̀ ni asà alágbára ti ṣègbé, asà Saulu, bí ẹni pé a kò fi òróró yàn án. “Ọrun Jonatani kì í padà bẹ́ẹ̀ ni idà Saulu kì í padà lásán, láì kan ẹ̀jẹ̀ àwọn tí a pa, àti ẹran àwọn alágbára. Saulu àti Jonatani— ní ọjọ́ ayé, wọ́n fẹ́ràn ara, wọn sì dùn, ní ikú, wọn kò sì yà ara wọ́n. Wọ́n yára ju idì lọ, wọ́n lágbára ju kìnnìún lọ. “Ẹ̀yin ọmọbìnrin Israẹli, ẹ sọkún lórí Saulu, ẹni tí ó fi aṣọ ọ̀gbọ̀ dáradára wọ̀ yín, ẹni tí ó fi wúrà sí ara aṣọ yín. “Wò ó bí alágbára ti ṣubú ní ojú ogun! Jonatani, ìwọ tí a pa ní òkè gíga. Ọkàn mi gbọgbẹ́ fún ọ Jonatani arákùnrin mi; ìwọ ṣọ̀wọ́n fún mi. Ìfẹ́ rẹ sí mi jẹ́ ìyanu, ó jẹ́ ìyanu ju ti obìnrin lọ. “Wò ó bí alágbára ti ṣubú! Ohun ìjà sì ti ṣègbé!”