II. Sam 1:17-27

II. Sam 1:17-27 YBCV

Dafidi si fi orin ọ̀fọ yi ṣọ̀fọ̀ lori Saulu ati lori Jonatani ọmọ rẹ̀: O si pa aṣẹ lati kọ́ awọn ọmọ Juda ni ilò ọrun: wõ, a ti kọ ọ sinu iwe Jaṣeri. Ẹwà rẹ Israeli li a pa li oke giga rẹ: wò bi awọn alagbara ti ṣubu! Ẹ máṣe sọ ọ ni Gati, ẹ má si ṣe kokiki rẹ̀ ni igboro Aṣkeloni; ki awọn ọmọbinrin Filistini ki o má ba yọ̀, ki ọmọbinrin awọn alaikọla ki o má ba yọ̀. Ẹnyin oke Gilboa, ki ìri ki o má si, ati ki ojò ki o má rọ̀ si nyin, ki ẹ má si ni oko ọrẹ ẹbọ: nitori nibẹ li a gbe sọ asà awọn alagbara nu, asà Saulu, bi ẹnipe a ko fi ororo yàn a. Ọrun Jonatani ki ipada, ati idà Saulu ki ipada lasan lai kan ẹjẹ awọn ti a pa, ati ọra awọn alagbara. Saulu ati Jonatani ni ifẹni si ara wọn, nwọn si dùn li ọjọ aiye wọn, ati ni ikú wọn, nwọn kò ya ara wọn: nwọn yara ju idì lọ, nwọn si li agbara ju kiniun lọ. Ẹnyin ọmọbinrin Israeli, ẹ sọkun lori Saulu, ti o fi aṣọ òdodó ati ohun ọṣọ́ wọ̀ nyin, ti o fi ohun ọṣọ́ wura si ara aṣọ nyin. Wo bi awọn alagbara ti ṣubu larin ogun! A Jonatani! iwọ ti a pa li oke giga rẹ! Wahala ba mi nitori rẹ, Jonatani, arakunrin mi: didùn jọjọ ni iwọ jẹ fun mi: ifẹ rẹ si mi jasi iyanu, o jù ifẹ obinrin lọ. Wo bi awọn alagbara ti ṣubu, ati bi ohun ija ti ṣegbe!