I. A. Ọba 6:19-38

I. A. Ọba 6:19-38 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ibi-mimọ́-julọ na li o mura silẹ ninu ile lati gbe apoti majẹmu Oluwa kà ibẹ. Ibi-mimọ́-julọ na si jasi ogún igbọnwọ ni gigùn, li apa ti iwaju, ati ogún igbọnwọ ni ibú, ati ogún igbọnwọ ni giga rẹ̀; o si fi wura ailadàlu bò o, bẹ̃li o si fi igi kedari bò pẹpẹ. Solomoni si fi wura ailadàlu bò ile na ninu: o si fi ẹwọ́n wura ṣe oju ibi-mimọ́-julọ, o si fi wura bò o. Gbogbo ile na li o si fi wura bò titi o fi pari gbogbo ile na; ati gbogbo pẹpẹ ti o wà niha ibi-mimọ́-julọ li o fi wura bò. Ati ninu ibi-mimọ́-julọ li o fi igi olifi ṣe kerubu meji, ọkọkan jẹ igbọnwọ mẹwa ni giga. Ati igbọnwọ marun ni apa kerubu kan, ati igbọnwọ marun ni apa kerubu keji; lati igun apakan titi de igun apa-keji jẹ igbọnwọ mẹwa. Igbọnwọ mẹwa si ni kerubu keji: kerubu mejeji jẹ ìwọn kanna ati titobi kanna. Giga kerubu kan jẹ igbọnwọ mẹwa, bẹ̃ni ti kerubu keji. O si fi awọn kerubu sinu ile ti inu lọhun, nwọn si nà iyẹ-apa kerubu na, tobẹ̃ ti iyẹ-apa ọkan si kàn ogiri kan, ati iyẹ-apa kerubu keji si kàn ogiri keji: iyẹ-apa wọn si kàn ara wọn larin ile na. O si fi wura bò awọn kerubu na. O si yá aworan awọn kerubu lara gbogbo ogiri ile na yikakiri ati ti igi-ọpẹ, ati ti itanna eweko, ninu ati lode. Ilẹ ile na li o fi wura tẹ́ ninu ati lode. Ati fun oju-ọ̀na ibi-mimọ́-julọ li o ṣe ilẹkùn igi olifi: itẹrigbà ati opó ihà jẹ idamarun ogiri. Ilẹkùn mejeji na li o si fi igi olifi ṣe; o si yá aworan awọn kerubu ati ti igi-ọpẹ, ati ti itanna eweko sara wọn, o si fi wura bò wọn, o si nà wura si ara awọn kerubu, ati si ara igi-ọpẹ. Bẹ̃li o si ṣe opó igi olifi olorigun mẹrin fun ilẹkun tempili na. Ilẹkun mejeji si jẹ ti igi firi: awẹ́ meji ilẹkun kan jẹ iṣẹ́po, ati awẹ́ meji ilẹkun keji si jẹ iṣẹ́po. O si yá awọn kerubu, ati igi-ọpẹ, ati itanna eweko si ara wọn: o si fi wura bò o, eyi ti o tẹ́ sori ibi ti o gbẹ́. O si fi ẹsẹsẹ mẹta okuta gbigbẹ́, ati ẹsẹ kan ìti kedari kọ́ agbala ti inu ọhun. Li ọdun kẹrin li a fi ipilẹ ile Oluwa le ilẹ̀, li oṣu Sifi. Ati li ọdun kọkanla, li oṣu Bulu, ti iṣe oṣu kẹjọ, ni ile na pari jalẹ-jalẹ, pẹlu gbogbo ipin rẹ̀, gẹgẹ bi gbogbo eyi ti o yẹ: o si fi ọdun meje kọ́ ọ.

I. A. Ọba 6:19-38 Yoruba Bible (YCE)

Wọ́n kọ́ ibi mímọ́ kan sí ọwọ́ ẹ̀yìn ilé ìsìn náà, inú ibi mímọ́ yìí ni wọ́n gbé Àpótí Ẹ̀rí OLUWA sí. Gígùn ibi mímọ́ ti inú yìí jẹ́ ogún igbọnwọ, ó fẹ̀ ní ogún igbọnwọ, gíga rẹ̀ náà sì jẹ́ ogún igbọnwọ. Ojúlówó wúrà ni wọ́n fi bo gbogbo ibi mímọ́ náà; wọ́n sì fi pákó igi kedari ṣe pẹpẹ kan sibẹ. Ojúlówó wúrà ni Solomoni fi bo gbogbo inú ilé ìsìn náà, wọ́n sì so ẹ̀wọ̀n kan, ó fi dábùú ẹnu ọ̀nà ibi mímọ́ ti inú, ó sì yọ́ wúrà bò ó. Gbogbo inú ilé ìsìn náà patapata ni wọ́n fi wúrà bò, ati pẹpẹ tí ó wà ninu Ibi-Mímọ́-Jùlọ. Wọ́n fi igi olifi gbẹ́ ẹ̀dá abìyẹ́ meji tí wọn ń pè ní Kerubu, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ga ní igbọnwọ mẹ́wàá, wọ́n kó wọn sinu Ibi-Mímọ́-Jùlọ náà. Ìyẹ́ kọ̀ọ̀kan àwọn Kerubu mejeeji gùn ní igbọnwọ marun-un, tí ó fi jẹ́ pé láti ṣóńṣó ìyẹ́ kinni Kerubu kọ̀ọ̀kan dé ṣóńṣo ìyẹ́ rẹ̀ keji jẹ́ igbọnwọ mẹ́wàá. Gígùn ìyẹ́ mejeeji Kerubu keji náà jẹ́ igbọnwọ mẹ́wàá. Bákan náà ni àwọn Kerubu mejeeji yìí rí, bákan náà sì ni títóbi wọn. Ekinni keji wọn ga ní igbọnwọ mẹ́wàá. Ó gbé wọn kalẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ ara wọn ninu Ibi-Mímọ́-Jùlọ. Àwọn mejeeji na ìyẹ́ wọn tí ó fi jẹ́ pé ọ̀kan ninu àwọn ìyẹ́ Kerubu kinni kan ògiri yàrá ní ẹ̀gbẹ́ kan, ọ̀kan ninu àwọn ìyẹ́ Kerubu keji sì kan ògiri yàrá ní ẹ̀gbẹ́ keji. Ìyẹ́ keji Kerubu kinni ati ìyẹ́ kinni Kerubu keji sì kan ara wọn ní ààrin yàrá náà. Wúrà ni wọ́n yọ́ bo àwọn Kerubu náà. Wọ́n gbẹ́ àwòrán igi ọ̀pẹ, ati ti òdòdó, ati ti Kerubu yípo ara ògiri yàrá tí ó wà ninu ati èyí tí ó wà lóde; wọ́n sì yọ́ wúrà bo ilẹ̀ àwọn yàrá náà. Wọ́n ri ìlẹ̀kùn meji, alápapọ̀, tí wọ́n fi igi olifi ṣe, mọ́ ẹnu ọ̀nà Ibi-Mímọ́-Jùlọ. Àtẹ́rígbà ìlẹ̀kùn náà rí ṣóńṣó ní ààrin, wọ́n gbẹ́ igi ọ̀pẹ, ati òdòdó, ati kerubu sí ara àwọn ìlẹ̀kùn náà; wọ́n sì yọ́ wúrà bò wọ́n patapata: ati igi ọ̀pẹ, ati òdòdó, ati àwọn Kerubu náà. Wọ́n fi igi olifi ṣe férémù ìlẹ̀kùn onígun mẹrin, wọ́n rì í mọ́ ẹnu ọ̀nà àbáwọ gbọ̀ngàn ńlá. Wọn fi igi sipirẹsi ṣe ìlẹ̀kùn meji, ekinni keji ní awẹ́ meji, awẹ́ ekinni keji sì ṣe é pàdé mọ́ ara wọn. Wọ́n gbẹ́ igi ọ̀pẹ, ati òdòdó, ati àwọn kerubu sí ara àwọn ìlẹ̀kùn náà, wọ́n sì fi wúrà bo gbogbo wọn. Bí wọ́n ṣe mọ ògiri àgbàlá inú ilé ìsìn náà ni pé, bí wọ́n bá mọ ìlè òkúta mẹta wọn a mọ ìlè igi kedari kan. Ninu oṣù Sifi, ní ọdún kẹrin ìjọba Solomoni, ni wọ́n fi ìpìlẹ̀ ilé ìsìn náà sọlẹ̀. Ninu oṣù Bulu, ní ọdún kọkanla ìjọba Solomoni ni wọ́n kọ́ ilé ìsìn náà parí patapata, ó sì rí bí wọ́n ti ṣètò pé kó rí gẹ́lẹ́. Ọdún meje ni ó gba Solomoni láti parí rẹ̀.

I. A. Ọba 6:19-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ó sì múra ibi mímọ́ jùlọ sílẹ̀ nínú ilé náà láti gbé àpótí ẹ̀rí OLúWA ka ibẹ̀. Inú ibi mímọ́ náà sì jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, ogún ìgbọ̀nwọ́ ní ìbú, àti ogún ìgbọ̀nwọ́ ní gíga. Ó sì fi kìkì wúrà bo inú rẹ̀ ó sì fi igi kedari bo pẹpẹ rẹ̀. Solomoni sì fi kìkì wúrà bo inú ilé náà, ó sì tan ẹ̀wọ̀n wúrà dé ojú ibi mímọ́ jùlọ, ó sì fi wúrà bò ó. Gbogbo ilé náà ni ó fi wúrà bò títí ó fi parí gbogbo ilé náà, àti gbogbo pẹpẹ tí ó wà níhà ibi mímọ́ jùlọ, ni ó fi wúrà bò. Ní inú ibi mímọ́ jùlọ ni ó fi igi olifi ṣe kérúbù méjì, ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ní gíga. Apá kérúbù kìn-ín-ní sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gíga, àti apá kérúbù kejì ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún; ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá láti ṣóńṣó apá kan dé ṣóńṣó apá kejì. Ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá sì ni kérúbù kejì pẹ̀lú, nítorí kérúbù méjèèjì jọ ara wọn ní ìwọ̀n ní títóbi àti títẹ̀wọ̀n bákan náà. Gíga kérúbù kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá. Ó sì gbé àwọn kérúbù náà sínú ilé ti inú lọ́hùn ún, pẹ̀lú ìyẹ́ apá wọn ní nínà jáde. Ìyẹ́ apá kérúbù kan sì kan ògiri kan, nígbà tí ìyẹ́ apá èkejì sì kan ògiri kejì, ìyẹ́ apá wọn sì kan ara wọn láàrín yàrá náà. Ó sì fi wúrà bo àwọn kérúbù náà. Lára àwọn ògiri tí ó yí ilé náà ká, nínú àti lóde, ó sì ya àwòrán àwọn kérúbù sí i àti ti igi ọ̀pẹ, àti ti ìtànná ewéko. Ó sì tún fi wúrà tẹ́ ilẹ̀ ilé náà nínú àti lóde. Nítorí ojú ọ̀nà ibi mímọ́ jùlọ ni ó ṣe ìlẹ̀kùn igi olifi sí pẹ̀lú àtẹ́rígbà àti òpó ìhà jẹ́ ìdámárùn-ún ògiri. Àti lára ìlẹ̀kùn igi olifi náà ni ó ya àwòrán àwọn kérúbù, igi ọ̀pẹ àti ti ìtànná ewéko sí, ó sì fi wúrà bò wọ́n, ó sì tan wúrà sí ara àwọn kérúbù àti sí ara igi ọ̀pẹ. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì ṣe òpó igi olifi onígun mẹ́rin fún ìlẹ̀kùn ilé náà. Ó sì tún fi igi firi ṣe ìlẹ̀kùn méjì, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì ní ewé méjì tí ó yí sí ihò ìtẹ̀bọ̀. Ó sì ya àwòrán kérúbù, àti ti igi ọ̀pẹ àti ti ìtànná ewéko sí ara wọn, ó sì fi wúrà bò ó, èyí tí ó tẹ́ sórí ibi tí ó gbẹ́. Ó sì fi ẹsẹẹsẹ òkúta mẹ́ta gbígbẹ, àti ẹsẹ̀ kan ìtí kedari kọ́ àgbàlá ti inú lọ́hùn ún. Ní ọdún kẹrin ni a fi ìpìlẹ̀ ilé OLúWA lé ilẹ̀, ní oṣù Sifi. Ní ọdún kọkànlá ní oṣù Bulu, oṣù kẹjọ, a sì parí ilé náà jálẹ̀ jálẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ìpín rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí ó yẹ. Ó sì lo ọdún méje ní kíkọ́ ilé náà.