I. A. Ọba 6:19-38

I. A. Ọba 6:19-38 YBCV

Ibi-mimọ́-julọ na li o mura silẹ ninu ile lati gbe apoti majẹmu Oluwa kà ibẹ. Ibi-mimọ́-julọ na si jasi ogún igbọnwọ ni gigùn, li apa ti iwaju, ati ogún igbọnwọ ni ibú, ati ogún igbọnwọ ni giga rẹ̀; o si fi wura ailadàlu bò o, bẹ̃li o si fi igi kedari bò pẹpẹ. Solomoni si fi wura ailadàlu bò ile na ninu: o si fi ẹwọ́n wura ṣe oju ibi-mimọ́-julọ, o si fi wura bò o. Gbogbo ile na li o si fi wura bò titi o fi pari gbogbo ile na; ati gbogbo pẹpẹ ti o wà niha ibi-mimọ́-julọ li o fi wura bò. Ati ninu ibi-mimọ́-julọ li o fi igi olifi ṣe kerubu meji, ọkọkan jẹ igbọnwọ mẹwa ni giga. Ati igbọnwọ marun ni apa kerubu kan, ati igbọnwọ marun ni apa kerubu keji; lati igun apakan titi de igun apa-keji jẹ igbọnwọ mẹwa. Igbọnwọ mẹwa si ni kerubu keji: kerubu mejeji jẹ ìwọn kanna ati titobi kanna. Giga kerubu kan jẹ igbọnwọ mẹwa, bẹ̃ni ti kerubu keji. O si fi awọn kerubu sinu ile ti inu lọhun, nwọn si nà iyẹ-apa kerubu na, tobẹ̃ ti iyẹ-apa ọkan si kàn ogiri kan, ati iyẹ-apa kerubu keji si kàn ogiri keji: iyẹ-apa wọn si kàn ara wọn larin ile na. O si fi wura bò awọn kerubu na. O si yá aworan awọn kerubu lara gbogbo ogiri ile na yikakiri ati ti igi-ọpẹ, ati ti itanna eweko, ninu ati lode. Ilẹ ile na li o fi wura tẹ́ ninu ati lode. Ati fun oju-ọ̀na ibi-mimọ́-julọ li o ṣe ilẹkùn igi olifi: itẹrigbà ati opó ihà jẹ idamarun ogiri. Ilẹkùn mejeji na li o si fi igi olifi ṣe; o si yá aworan awọn kerubu ati ti igi-ọpẹ, ati ti itanna eweko sara wọn, o si fi wura bò wọn, o si nà wura si ara awọn kerubu, ati si ara igi-ọpẹ. Bẹ̃li o si ṣe opó igi olifi olorigun mẹrin fun ilẹkun tempili na. Ilẹkun mejeji si jẹ ti igi firi: awẹ́ meji ilẹkun kan jẹ iṣẹ́po, ati awẹ́ meji ilẹkun keji si jẹ iṣẹ́po. O si yá awọn kerubu, ati igi-ọpẹ, ati itanna eweko si ara wọn: o si fi wura bò o, eyi ti o tẹ́ sori ibi ti o gbẹ́. O si fi ẹsẹsẹ mẹta okuta gbigbẹ́, ati ẹsẹ kan ìti kedari kọ́ agbala ti inu ọhun. Li ọdun kẹrin li a fi ipilẹ ile Oluwa le ilẹ̀, li oṣu Sifi. Ati li ọdun kọkanla, li oṣu Bulu, ti iṣe oṣu kẹjọ, ni ile na pari jalẹ-jalẹ, pẹlu gbogbo ipin rẹ̀, gẹgẹ bi gbogbo eyi ti o yẹ: o si fi ọdun meje kọ́ ọ.