I. Kro 7:13-40
I. Kro 7:13-40 Bibeli Mimọ (YBCV)
Awọn ọmọ Naftali: Jasieli, ati Guni, ati Jeseri, ati Ṣallumu, awọn ọmọ Bilha. Awọn ọmọ Manasse; Aṣrieli, ti aya rẹ̀ bi: (ṣugbọn obinrin rẹ̀, ara Aramu, bi Makiri baba Gileadi: Makiri si mu arabinrin Huppimu, ati Ṣuppimu li aya, orukọ arabinrin ẹniti ijẹ Maaka,) ati orukọ ekeji ni Selofehadi: Selofehadi si ni awọn ọmọbinrin. Maaka, obinrin Makiri, bi ọmọ, on si pè orukọ rẹ̀ ni Pereṣi: orukọ arakunrin rẹ̀ ni Ṣereṣi; ati awọn ọmọ rẹ̀ ni Ulamu ati Rakemu. Awọn ọmọ Ulamu: Bedani. Awọn wọnyi li awọn ọmọ Gileadi, ọmọ Makiri, ọmọ Manasse. Arabinrin rẹ̀, Hammoleketi, bi Iṣodi, ati Abieseri, ati Mahala. Ati awọn ọmọ Ṣemida ni, Ahiani, ati Ṣekemu, ati Likki, ati Aniamu. Awọn ọmọ Efraimu: Ṣutela, ati Beredi ọmọ rẹ̀, ati Tahati, ọmọ rẹ̀, ati Elada, ọmọ rẹ̀, ati Tahati ọmọ rẹ̀. Ati Sabadi ọmọ rẹ̀, ati Ṣutela ọmọ rẹ̀, ati Eseri, ati Eleadi, ẹniti awọn ọkunrin Gati, ti a bi ni ilẹ na, pa, nitori nwọn sọkalẹ wá lati kó ẹran ọ̀sin wọn lọ. Efraimu baba wọn si ṣọ̀fọ li ọjọ pupọ, awọn arakunrin rẹ̀ si wá lati tù u ninu. Nigbati o si wọle tọ̀ aya rẹ̀ lọ, o loyun o si bi ọmọ kan, on si pè orukọ rẹ̀ ni Beria, nitoriti ibi ba ile rẹ̀. Ọmọ rẹ̀ obinrin ni Sera, ẹniti o tẹ̀ Bet-horoni dó, ti isalẹ ati ti òke, ati Usseni Ṣera. Refa si ni ọmọ rẹ̀ ọkunrin, Reṣefu pẹlu, ati Tela ọmọ rẹ̀, ati Tahani ọmọ rẹ̀. Laadani ọmọ rẹ̀, Ammihudi ọmọ rẹ̀, Eliṣama ọmọ rẹ̀. Nuni ọmọ rẹ̀, Joṣua ọmọ rẹ̀, Ati awọn ini ati ibugbe wọn ni Beteli, ati ilu rẹ̀, ati niha ìla-õrùn Naarani, niha ìwọ-õrùn Geseri pẹlu ilu rẹ̀: Ṣekemu pẹlu ati ilu rẹ̀, titi de Gasa ilu rẹ̀: Ati leti ilu awọn ọmọ Manasse, Betṣeani, ati ilu rẹ̀, Taanaki ati ilu rẹ̀, Megiddo ati ilu rẹ̀, Dori ati ilu rẹ̀. Ninu awọn wọnyi li awọn ọmọ Josefu, ọmọ Israeli, ngbe. Awọn ọmọ Aṣeri: Imna, ati Iṣua, ati Iṣuai, ati Beria, ati Sera, arabinrin wọn. Awọn ọmọ Beria: Heberi, ati Malkieli, ti iṣe baba Birsafiti. Heberi si bi Jafleti, ati Ṣomeri, ati Hotamu, ati Ṣua, arabinrin wọn. Ati awọn ọmọ Jafleti: Pasaki, ati Bimhali, ati Aṣfati. Wọnyi li awọn omọ Jafleti. Awọn ọmọ Ṣameri: Ahi, ati Roga, Jehubba, ati Aramu. Awọn ọmọ arakunrin rẹ̀ Helemu: Sofa, ati Imna, ati Ṣeleṣi, ati Amali. Awọn ọmọ Sofa; Sua, ati Harneferi, ati Ṣuali, ati Beri, ati Imra, Beseri, ati Hodi, ati Ṣamma, ati Ṣilṣa, ati Itrani, ati Beera. Ati awọn ọmọ Jeteri: Jefunne, ati Pispa, ati Ara. Ati awọn ọmọ Ulla: Ara, ati Hanieli, ati Resia. Gbogbo awọn wọnyi li awọn ọmọ Aṣeri, awọn olori ile baba wọn, aṣayan alagbara akọni enia, olori ninu awọn ijoye. Iye awọn ti a kà yẹ fun ogun, ati fun ijà ni idile wọn jẹ, ẹgbã mẹtala ọkunrin.
I. Kro 7:13-40 Yoruba Bible (YCE)
Nafutali bí ọmọ mẹrin: Jasieli, Guni, Jeseri, ati Ṣalumu. Biliha ni ìyá baba wọn. Manase fẹ́ obinrin kan, ará Aramea; ọmọ meji ni obinrin náà bí fún un; Asirieli, ati Makiri, baba Gileadi. Makiri fẹ́ iyawo kan ará Hupi, ati ọ̀kan ará Ṣupimu. Orúkọ arabinrin rẹ̀ ni Maaka. Orúkọ ọmọ rẹ̀ keji ni Selofehadi; tí gbogbo ọmọ tirẹ̀ jẹ́ kìkì obinrin. Maaka, Iyawo Makiri, bí ọmọ meji: Pereṣi ati Ṣereṣi. Ṣereṣi ni ó bí Ulamu ati Rakemu; Ulamu sì bí Bedani. Àwọn ni ọmọ Gileadi, ọmọ Makiri, ọmọ Manase. Arabinrin Gileadi kan tí ń jẹ́ Hamoleketu ni ó bí Iṣodu, Abieseri, ati Mahila. Ṣemida bí ọmọkunrin mẹrin: Ahiani, Ṣekemu, Liki, ati Aniamu. Àwọn arọmọdọmọ Efuraimu nìwọ̀nyí: Ṣutela ni baba Beredi, baba Tahati, baba Eleada, baba Tahati, baba Sabadi, baba Ṣutela, Eseri, ati Eleadi; Eseri ati Eleadi yìí ni àwọn ará ìlú Gati pa nígbà tí wọ́n lọ kó ẹran ọ̀sìn àwọn ará Gati. Baba wọn, Efuraimu, ṣọ̀fọ̀ wọn fún ọpọlọpọ ọjọ́. Àwọn arakunrin rẹ̀ bá wá láti tù ú ninu. Lẹ́yìn náà, Efuraimu bá aya rẹ̀ lòpọ̀, ó lóyún, ó sì bí ọmọkunrin kan. Ó sọ ọmọ náà ní Beraya nítorí ibi tí ó dé bá ìdílé wọn. Efuraimu ní ọmọbinrin kan tí ń jẹ́ Ṣeera, òun ló kọ́ ìlú Beti Horoni ti òkè ati ti ìsàlẹ̀, ati Useni Ṣeera. Orúkọ àwọn ọmọ ati arọmọdọmọ Efuraimu yòókù ni Refa, baba Reṣefu, baba Tela, baba Tahani; baba Ladani, baba Amihudu, baba Eliṣama; baba Nuni, baba Joṣua. Àwọn ilẹ̀ ìní wọn ati àwọn agbègbè tí wọ́n tẹ̀dó sí nìwọ̀nyí: Bẹtẹli, Naarani ní apá ìlà oòrùn, Geseri ní apá ìwọ̀ oòrùn, Ṣekemu ati Aya; pẹlu àwọn ìletò tí ó wà lẹ́bàá àyíká wọn. Àwọn ìlú wọnyi wà lẹ́bàá ààlà ilẹ̀ àwọn ará Manase: Beti Ṣani, Taanaki, Megido, Dori ati gbogbo ìlú tí ó yí wọn ká. Níbẹ̀ ni àwọn ìran Josẹfu, ọmọ Jakọbu ń gbé. Àwọn ọmọ Aṣeri nìwọ̀nyí: Imina, Iṣifa, Iṣifi ati Beraya, ati ọmọbinrin kan tí ń jẹ́ Sera. Beraya bí ọmọkunrin meji: Heberi ati Malikieli, baba Birisaiti. Heberi bí ọmọkunrin mẹta: Jafileti, Ṣomeri ati Hotamu; ati ọmọbinrin kan tí ń jẹ́ Ṣua. Jafileti bí ọmọ mẹta: Pasaki, Bimihali, ati Aṣifatu. Ṣomeri, arakunrin Jafileti, bí ọmọkunrin mẹta: Roga, Jehuba ati Aramu. Hotamu, arakunrin rẹ̀, bí ọmọkunrin mẹrin: Sofa, Imina, Ṣeleṣi ati Amali. Sofa bí Ṣua, Haneferi, ati Ṣuali; Beri, ati Imira; Beseri, Hodi, ati Ṣama, Ṣiliṣa, Itirani, ati Beera. Jeteri bí: Jefune, Pisipa, ati Ara. Ula bí: Ara, Hanieli ati Risia. Àwọn ni ìran Aṣeri, wọ́n jẹ́ baálé baálé ni ìdílé baba wọn, àṣàyàn akọni jagunjagun, ati olórí láàrin àwọn ìjòyè. Àkọsílẹ̀ iye àwọn tí wọ́n tó ogun jà ninu wọn, ní ìdílé ìdílé jẹ́ ẹgbaa mẹtala (26,000).
I. Kro 7:13-40 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn ọmọ Naftali: Jasieli, Guni, Jeseri àti Ṣallumu—ọmọ rẹ̀ nípa Biliha. Àwọn ìran ọmọ Manase: Asrieli jẹ́ ìran ọmọ rẹ̀ ní ipasẹ̀ àlè rẹ̀ ará Aramu ó bí Makiri baba Gileadi. Makiri sì mú ìyàwó láti àárín àwọn ará Huppimu àti Ṣuppimu. Orúkọ arábìnrin rẹ̀ a máa jẹ́ Maaka. Orúkọ ìran ọmọ mìíràn a máa jẹ́ Ṣelofehadi, tí ó ní àwọn ọmọbìnrin nìkan ṣoṣo. Maaka, ìyàwó Makiri bí ọmọkùnrin kan. Ó sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Peresi. Ó sì pe arákùnrin rẹ̀ ní Ṣereṣi, àwọn ọmọ rẹ̀ sì ní Ulamu àti Rakemu. Ọmọ Ulamu: Bedani. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Gileadi ọmọ Makiri, ọmọ Manase. Arábìnrin rẹ̀. Hamoleketi bí Iṣhodi, Abieseri àti Mahila. Àwọn ọmọ Ṣemida sì jẹ́: Ahiani, Ṣekemu, Likki àti Aniamu. Àwọn ìran ọmọ Efraimu: Ṣutelahi, Beredi ọmọkùnrin rẹ̀, Tahati ọmọ rẹ̀, Eleadah ọmọ rẹ̀. Tahati ọmọ rẹ̀ Sabadi ọmọ, rẹ̀, àti Ṣutelahi ọmọ rẹ̀. Eseri àti Eleadi ni a pa nípasẹ̀ àwọn ọkùnrin bíbí ìbílẹ̀ Gati Nígbà tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ láti lọ fi agbára mú ohun ọ̀sìn wọn Efraimu baba wọn ṣọ̀fọ̀ fún wọn ní ọjọ́ púpọ̀, àwọn ìbátan rẹ̀ wá láti tù ú nínú. Nígbà náà, ó sùn pẹ̀lú, ìyàwó rẹ̀, ó sì lóyún ó sì bí ọmọkùnrin kan. Ó sì sọ ọ́ ní Beriah nítorí òfò ti wà nínú ìdílé náà. Ọmọbìnrin rẹ̀ sì jẹ́ Ṣerah, ẹni tí ó kọ́ ìsàlẹ̀ àti òkè Beti-Horoni àti Useni-Ṣerah pẹ̀lú. Refa jẹ́ ọmọ rẹ̀, Resefi ọmọ rẹ̀, Tela ọmọ rẹ̀, Tahani ọmọ rẹ̀, Laadani ọmọ rẹ̀ Ammihudu ọmọ rẹ̀, Eliṣama ọmọ rẹ̀, Nuni ọmọ rẹ̀ àti Joṣua ọmọ rẹ̀. Ilẹ̀ wọn àti ìfìdíkalẹ̀ wọn ni Beteli àti àwọn ìletò tí ó yíká, Narani lọ sí ìhà ìlà-oòrùn, Geseri àti àwọn ìletò rẹ̀ lọ sí ìhà ìwọ̀-oòrùn àti Ṣekemu àti àwọn ìletò rẹ̀ ní ọ̀nà lọ sí Ayahi àti àwọn ìletò. Lẹ́gbẹ̀ ìpínlẹ̀ ti Manase ni Beti-Ṣeani, Taanaki, Megido àti Dori lápapọ̀ pẹ̀lú àwọn ìletò rẹ̀. Àwọn ìran ọmọ Josẹfu ọmọ Israẹli ń gbé nínú ìlú wọ̀nyí. Àwọn ọmọ Aṣeri: Imina, Iṣifa, Iṣfi àti Beriah. Arábìnrin wọn sì jẹ́ Sera. Àwọn ọmọ Beriah: Heberi àti Malkieli, tí ó jẹ́ baba Barsafiti. Heberi jẹ́ baba Jafileti, Ṣomeri àti Hotami àti ti arábìnrin wọn Ṣua. Àwọn ọmọ Jafileti: Pasaki, Bimhali àti Asifati. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Jafileti. Àwọn ọmọ Ṣomeri: Ahi, Roga, Jahuba àti Aramu. Àwọn ọmọ arákùnrin rẹ̀ Helemu Ṣofahi, Imina, Ṣeleṣi àti Amali. Àwọn ọmọ Ṣofahi: Sua, Haniferi, Ṣuali, Beri, Imra. Beseri, Hodi, Ṣama, Ṣilisa, Itrani àti Bera. Àwọn ọmọ Jeteri: Jefunne, Pisifa àti Ara. Àwọn ọmọ Ulla: Arah, Hannieli àti Reṣia. Gbogbo wọ̀nyí jẹ́ ìran ọmọ Aṣeri—olórí ìdílé, àṣàyàn ọkùnrin, alágbára jagunjagun àti olórí nínú àwọn ìjòyè. Iye àwọn tí a kà yẹ fún ogun, gẹ́gẹ́ bí à ti ṣe kọ ọ́ lẹ́sẹẹsẹ nínú ìtàn ìdílé wọn jẹ́ ẹgbàá-mẹ́tàlá (26,000) ọkùnrin.