Sekariah 1:14-17

Sekariah 1:14-17 YCB

Angẹli ti ń bá mi sọ̀rọ̀ sì wí fún mi pé, “Ìwọ kígbe wí pé: Báyìí ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí: ‘Èmi ń fi ìjowú ńlá jowú fún Jerusalẹmu àti fún Sioni. Èmi sì bínú púpọ̀púpọ̀ si àwọn orílẹ̀-èdè tí ó rò wí pé òun ní ààbò. Nítorí nígbà tí mo bínú díẹ̀, wọ́n ran ìparun lọ́wọ́ láti tẹ̀síwájú.’ “Nítorí náà, báyìí ni OLúWA wí: ‘Mo padà tọ Jerusalẹmu wá pẹ̀lú àánú; ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí, a ó kọ́ ilé mi sínú rẹ̀, a o sí ta okùn ìwọ̀n kan jáde sórí Jerusalẹmu.’ “Máa ké síbẹ̀ pé: Báyìí ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí: ‘A o máa fi ìre kún ìlú ńlá mi síbẹ̀; OLúWA yóò sì máa tu Sioni nínú síbẹ̀, yóò sì yan Jerusalẹmu síbẹ̀.’ ”