Saamu 51:3-6

Saamu 51:3-6 YCB

Nítorí mo mọ̀ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi, nígbà gbogbo ni ẹ̀ṣẹ̀ mi wà níwájú mi. Sí ọ, ìwọ nìkan ṣoṣo, ni mo dẹ́ṣẹ̀ sí ni mo sì ṣe búburú níwájú rẹ̀, kí a lè dá ọ láre nígbà tí ìwọ bá ń sọ̀rọ̀, kí o sì le wà láìlẹ́bi, nígbà tí ìwọ bá ń ṣe ìdájọ́. Nítòótọ́, nínú ẹ̀ṣẹ̀ ni a ti bí mi, nínú ẹ̀ṣẹ̀ ni ìyá mí sì lóyún mi. Nítòótọ́ ìwọ fẹ́ òtítọ́ ní inú; ìwọ kọ́ mi ní ọgbọ́n ní ìhà ìkọ̀kọ̀.