Ènìyàn búburú fa idà yọ, wọ́n sì tẹ àwọn ọrun wọn, láti sọ tálákà àti aláìní kalẹ̀, láti pa àwọn tí ó dúró ṣinṣin. Idà wọn yóò wọ àyà wọn lọ, àti wí pé ọrun wọn yóò sì ṣẹ́. Ohun díẹ̀ tí olódodo ní, sàn ju ọ̀pọ̀ ọrọ̀ ènìyàn búburú; nítorí pé a óò ṣẹ́ ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú, ṣùgbọ́n OLúWA gbé olódodo sókè. OLúWA mọ àwọn ọjọ́ àwọn tó dúró ṣinṣin, àti wí pé ilẹ̀ ìní wọn yóò wà títí ayérayé; Ojú kì yóò tì wọ́n ní àkókò ibi, àti ní ọjọ́ ìyàn, a ó tẹ́ wọn lọ́rùn. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn búburú yóò ṣègbé. Àwọn ọ̀tá OLúWA yóò dàbí ẹwà oko tútù; wọn fò lọ; bi èéfín ni wọn yóò fò lọ kúrò. Àwọn ènìyàn búburú yá, wọn kò sì san án padà, ṣùgbọ́n àwọn olódodo a máa ṣàánú, a sì máa fi fún ni; Nítorí àwọn tí OLúWA bá bùkún ni yóò jogún ilẹ̀ náà, àwọn tí ó fi bú ni a ó gé kúrò. Ìlànà ìgbésẹ̀ ènìyàn rere wá láti ọ̀dọ̀ OLúWA wá, o sì ṣe inú dídùn sí ọ̀nà rẹ̀; Bí ó tilẹ̀ ṣubú a kì yóò ta á nù pátápátá, nítorí tí OLúWA di ọwọ́ rẹ̀ mú. Èmi ti wà ni èwe, báyìí èmi sì dàgbà; síbẹ̀ èmi kò ì tí ì ri kí a kọ olódodo sílẹ̀, tàbí kí irú-ọmọ rẹ̀ máa ṣagbe oúnjẹ. Aláàánú ni òun nígbà gbogbo a máa yá ni; a sì máa bùsi i fún ni.
Kà Saamu 37
Feti si Saamu 37
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Saamu 37:14-26
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò