OLúWA, ìwọ tí wádìí mi, ìwọ sì ti mọ̀ mí. Ìwọ mọ̀ ìjókòó mi àti ìdìde mi, ìwọ mọ̀ èrò mi ní ọ̀nà jíjìn réré. Ìwọ yí ipa ọ̀nà mi ká àti ìdùbúlẹ̀ mi, gbogbo ọ̀nà mi sì di mí mọ̀ fún ọ. Nítorí tí kò sí ọ̀rọ̀ kan ní ahọ́n mi, kíyèsi i, OLúWA, ìwọ mọ̀ ọ́n pátápátá. Ìwọ sé mi mọ́ lẹ́yìn àti níwájú, ìwọ sì fi ọwọ́ rẹ lé mi. Irú ìmọ̀ yìí jẹ ohun ìyanu fún mi jù; ó ga, èmi kò le mọ̀ ọ́n. Níbo ní èmi yóò gbé lọ kúrò ni ọwọ́ ẹ̀mí rẹ? Tàbí níbo ni èmi yóò sáré kúrò níwájú rẹ? Bí èmi bá gòkè lọ sí ọ̀run, ìwọ wà níbẹ̀; bí èmí ba sì tẹ́ ẹní mi ní ipò òkú, kíyèsi i, ìwọ wà níbẹ̀ pẹ̀lú. Èmi ìbá mú ìyẹ́ apá òwúrọ̀, kí èmi sì lọ jókòó ní ìhà òpin Òkun; Àní, níbẹ̀ náà ni ọwọ́ rẹ̀ yóò fà mí ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì dì mímú.
Kà Saamu 139
Feti si Saamu 139
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Saamu 139:1-10
3 days
God has gone before us and protects us from behind. He has our battles already handled. He has the blindside covered. He isn’t surprised by curveballs. This focused 3-day devotional will leave you encouraged in the truth that God is the provider of the exact portion, the exact measure, for your life.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò