Òwe 4:20-23

Òwe 4:20-23 YCB

Ọmọ mi, tẹ́tí sí ohun tí mo sọ; fetísílẹ̀ dáradára sí ọ̀rọ̀ mi Má ṣe jẹ́ kí wọ́n rá mọ́ ọ lójú pa wọ́n mọ́ sínú ọkàn rẹ; Nítorí ìyè ni wọ́n jẹ́ fún gbogbo ẹni tí ó rí wọn àti ìlera fún gbogbo ara ènìyàn Ju gbogbo nǹkan tókù lọ, pa ọkàn rẹ mọ́ Nítorí òun ni orísun ìyè