ÌWÉ ÒWE 4:20-23

ÌWÉ ÒWE 4:20-23 YCE

Ọmọ mi, fetí sí ọ̀rọ̀ mi, tẹ́tí sílẹ̀ sí ohun tí mò ń sọ. Má jẹ́ kí wọn rú ọ lójú, fi wọ́n sọ́kàn. Nítorí pé ìyè ni wọ́n jẹ́ fún àwọn tí ó rí wọn, ati ìwòsàn fún gbogbo ẹran ara wọn. Ṣọ́ra pẹlu èrò ọkàn rẹ, nítorí èrò ọkàn ni orísun ìyè.