Òwe 11:1-11

Òwe 11:1-11 BMYO

OLúWA kórìíra òsùwọ̀n èké, ṣùgbọ́n òsùwọ̀n òtítọ́ jẹ́ inú dídùn un rẹ̀. Nígbà tí ìgbéraga bá dé, nígbà náà ni ìdójútì dé, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ ni ọgbọ́n ń wá. Òtítọ́ inú ẹni dídúró ṣinṣin ń ṣe amọ̀nà rẹ̀, ṣùgbọ́n aláìṣòótọ́ yóò parun nípasẹ̀ àìṣòótọ́ wọn. Ọ̀rọ̀ kò níláárí ní ọjọ́ ìbínú, ṣùgbọ́n òdodo a máa gbani lọ́wọ́ ikú. Òdodo aláìlẹ́gàn ṣe ọ̀nà tààrà fún wọn, ṣùgbọ́n ìwà búburú ènìyàn búburú yóò fà á lulẹ̀. Òdodo ẹni ìdúró ṣinṣin gbà wọ́n là, ṣùgbọ́n ìdẹ̀kùn ètè búburú mú aláìṣòótọ́. Nígbà tí ènìyàn búburú bá kú, ìrètí rẹ̀ a parun; gbogbo ohun tó ń fojú ṣọ́nà fún nípa agbára rẹ̀ já ṣófo. A gba olódodo kúrò lọ́wọ́ ibi dípò o rẹ̀, ibi wá sórí ènìyàn búburú. Aláìmọ Ọlọ́run fi ẹnu rẹ̀ ba aládùúgbò rẹ̀ jẹ́, ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ìmọ̀ olódodo sá àsálà. Nígbà tí olódodo ń gbèrú, ìlú a yọ̀; nígbà tí ènìyàn búburú parun, ariwo ayọ̀ gba ìlú kan. Nípasẹ̀ ìbùkún, olódodo a gbé ìlú ga: ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ẹnu ènìyàn búburú, a pa ìlú run.