Àwọn òwe Solomoni: ọlọ́gbọ́n ọmọ ń mú inú baba rẹ̀ dùn ṣùgbọ́n aṣiwèrè ọmọ ń ba inú ìyá rẹ̀ jẹ́. Ìṣúra tí a kójọ nípa ìwà búburú kò ní èrè ṣùgbọ́n òdodo a máa gbani lọ́wọ́ ikú. OLúWA kì í jẹ́ kí ebi máa pa olódodo ṣùgbọ́n ó ba ète àwọn ènìyàn búburú jẹ́. Ọwọ́ tí ó lẹ máa ń sọ ènìyàn di tálákà, ṣùgbọ́n ọwọ́ tí ó múra ṣíṣẹ́ a máa sọ ni di ọlọ́rọ̀. Ẹni tí ó kó irúgbìn jọ ní àsìkò òjò jẹ́ ọlọ́gbọ́n ọmọ, ṣùgbọ́n ẹni tí ó sùn ní àsìkò ìkórè jẹ́ adójútini ọmọ. Ìbùkún ní ó máa ń kún orí olódodo ṣùgbọ́n ìwà ipá máa ń kún ẹnu ènìyàn búburú. Ìrántí olódodo yóò jẹ́ ìbùkún ṣùgbọ́n orúkọ ènìyàn búburú yóò jẹrà. Ẹni tí ó gbọ́n nínú ọkàn rẹ̀ máa ń gba àṣẹ, ṣùgbọ́n ètè wérewère yóò parun. Ẹni tí ó ń rìn déédé, ń rìn láìléwu ṣùgbọ́n àṣírí ẹni tí ń rin ọ̀nà pálapàla yóò tú. Ẹni tí ń ṣẹ́jú pàkòpàkò fún ibi ń fa àìbalẹ̀ ọkàn aláìgbọ́n tí ń ṣàròyé kiri yóò parun. Ẹnu olódodo jẹ́ orísun ìyè ṣùgbọ́n ìwà ipá ni ó gba gbogbo ẹnu ènìyàn búburú.
Kà Òwe 10
Feti si Òwe 10
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Òwe 10:1-11
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò