OWE Solomoni ni wọnyi. Ọlọgbọ́n ọmọ ṣe inu-didùn baba rẹ̀, ṣugbọn aṣiwere ọmọ ni ibanujẹ iya rẹ̀. Iṣura ìwa-buburu kò li ère: ṣugbọn ododo ni igbani kuro lọwọ ikú. Oluwa kì yio jẹ ki ebi ki o pa ọkàn olododo; ṣugbọn o yi ifẹ awọn enia buburu danu. Ẹniti o ba dẹ̀ ọwọ a di talaka; ṣugbọn ọwọ awọn alãpọn ni imu ọlà wá. Ẹniti o ba kojọ ni igba-ẹ̀run li ọlọgbọ́n ọmọ: ṣugbọn ẹniti o ba nsùn ni igba ikore li ọmọ ti idoju tì ni. Ibukún wà li ori olododo: ṣugbọn ìwa-agbara ni yio bo ẹnu enia buburu. Ibukún ni iranti olõtọ: ṣugbọn orukọ enia buburu yio rà. Ọlọgbọ́n inu ni yio gbà ofin: ṣugbọn ete werewere li a o parun. Ẹniti o nrìn dede, o rìn dajudaju: ṣugbọn ẹniti o ba nṣe ayida ọ̀na rẹ̀, on li a o mọ̀. Ẹniti nṣẹ́ oju o mu ibanujẹ wá: ṣugbọn ète werewere li a o parun. Kanga ìye li ẹnu olododo: ṣugbọn ìwa-agbara ni yio bo ẹnu enia buburu.
Kà Owe 10
Feti si Owe 10
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Owe 10:1-11
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò