Filipi 4:10-14

Filipi 4:10-14 YCB

Èmi yọ̀ gidigidi nínú Olúwa pé, nísinsin yìí, ẹ̀yin tún ti sọjí nínú àníyàn ọkàn yín sí mi, nítòótọ́ ọkàn yín ń fàmọ́ mi ṣùgbọ́n ẹ kò ní àǹfààní tó. Kì í ṣe pé èmi ń sọ nítorí àìní: nítorí pé ni ipòkípò tí mo bá wà, mo tí kọ́ láti ní ìtẹ́lọ́rùn nínú rẹ̀. Mo mọ̀ ohun tí o jẹ láti wa nínú àìní, mo sì mọ ohun tí ó jẹ láti ni lọ́pọ̀lọpọ̀. Nínú ohunkóhun àti nínú ohun gbogbo mo ti kọ́ àṣírí láti máa jẹ́ àjẹyó tàbí láti wà ni àìjẹun, láti máa ni ànító àti láti ṣe aláìní. Èmi le ṣe ohun gbogbo nínú Kristi ẹni ti ń fi agbára fún mi. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ṣeun gidigidi ní ti pé ẹ̀yin ṣe alábápín nínú ìpọ́njú mi.