Bí èmi tìkára mi pẹ̀lú ti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ara. Bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun ni ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ara, tèmi tilẹ̀ pọ̀: Ẹni tí a kọ nílà ní ọjọ́ kẹjọ, láti inú kùkùté Israẹli wá, láti inú ẹ̀yà Benjamini, Heberu láti inú Heberu wá; nítorí, ní ti òfin Farisi ni èmi; Ní ti ìtara, èmi ń ṣe inúnibíni sí ìjọ; ní ti òdodo tí ó wà nínú òfin, mo jẹ́ aláìlẹ́gàn. Ṣùgbọ́n ohunkóhun tí ó ti jásí èrè fún mi, àwọn ni mo ti kà sí òfo nítorí Kristi. Nítòótọ́ láìṣe àní àní mo sì ka ohun gbogbo sí òfo nítorí ìtayọ ìmọ̀ Kristi Jesu Olúwa mi; nítorí ẹni ti mo ti ṣòfò ohun gbogbo, mo si kà wọn sí ohun tí kò ní èrè, kí èmi lè jèrè Kristi, Kí a sì lè bá mi nínú rẹ̀, láìní òdodo tí èmi tìkára mi, tí ó ti inú òfin wá, ṣùgbọ́n èyí tí ó ti inú ìgbàgbọ́ wá nínú Kristi, òdodo láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run nípasẹ̀ ìgbàgbọ́
Kà Filipi 3
Feti si Filipi 3
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Filipi 3:4-9
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò