Filipi 3:1-7

Filipi 3:1-7 YCB

Ní àkótán ará, ẹ máa yọ̀ nínú Olúwa wa. Kì í ṣe ìnira fún mi láti kọ̀wé ohun kan náà sí yín, ṣùgbọ́n fún yín ó jẹ́ ohun ààbò. Ẹ kíyèsára lọ́dọ̀ àwọn ajá, ẹ kíyèsára lọ́dọ̀ àwọn oníṣẹ́ búburú, ẹ sì kíyèsára lọ́dọ̀ àwọn onílà. Nítorí àwa ni onílà, tí ń sin Ọlọ́run nípa ti Ẹ̀mí, àwa sì ń ṣògo nínú Kristi Jesu, àwa kò sí ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ẹran-ara. Bí èmi tìkára mi pẹ̀lú ti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ara. Bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun ni ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ara, tèmi tilẹ̀ pọ̀: Ẹni tí a kọ nílà ní ọjọ́ kẹjọ, láti inú kùkùté Israẹli wá, láti inú ẹ̀yà Benjamini, Heberu láti inú Heberu wá; nítorí, ní ti òfin Farisi ni èmi; Ní ti ìtara, èmi ń ṣe inúnibíni sí ìjọ; ní ti òdodo tí ó wà nínú òfin, mo jẹ́ aláìlẹ́gàn. Ṣùgbọ́n ohunkóhun tí ó ti jásí èrè fún mi, àwọn ni mo ti kà sí òfo nítorí Kristi.