LI akotan, ará, ẹ mã yọ̀ ninu Oluwa. Kì iṣe inira fun mi lati kọwe ohun kanna si nyin, ṣugbọn fun nyin o jẹ ailewu. Ẹ kiyesara lọdọ awọn ajá, ẹ kiyesara lọdọ awọn oniṣẹ-buburu, ẹ kiyesara lọdọ awọn onilà. Nitori awa ni onilà, ti nsìn Ọlọrun nipa ti Ẹmí, awa si nṣogo ninu Kristi Jesu, awa kò si ni igbẹkẹle ninu ẹran-ara; Bi emi tikarami tilẹ ni igbẹkẹle ninu ara. Bi ẹnikẹni ba rò pe on ni igbẹkẹle ninu ara, temi tilẹ ju: Ẹniti a kọ nilà ni ijọ kẹjọ, lati inu kukuté Israeli wá, lati inu ẹ̀ya Benjamini, Heberu lati inu Heberu wá; niti ofin, Farisi li emi; Niti itara, emi nṣe inunibini si ijọ; niti ododo ti o wà ninu ofin, mo jẹ alailẹgan. Ṣugbọn ohunkohun ti o ti jasi ère fun mi, awọn ni mo ti kà si òfo nitori Kristi.
Kà Filp 3
Feti si Filp 3
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Filp 3:1-7
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò