Filipi 1:12-18

Filipi 1:12-18 YCB

Ǹjẹ́ èmi fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó mọ̀, ará, pé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí mi jásí àtẹ̀gùn sí ìlọsíwájú ìhìnrere. Nítorí ìdí èyí, ó ti hàn gbangba sí gbogbo àwọn ẹ̀ṣọ́ ààfin àti sí àwọn ẹlòmíràn wí pé mo wà nínú ìdè fún Kristi. Nítorí ìdè mi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ará nínú Olúwa ni a ti mú lọ́kàn le láti sọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí i pẹ̀lú ìgboyà àti láìbẹ̀rù. Òtítọ́ ni pé àwọn ẹlòmíràn tilẹ̀ ń fi ìjà àti ìlara wàásù Kristi, ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmíràn sì ń fi inú rere ṣe é. Àwọn kan ń fi ìjà wàásù Kristi, kì í ṣe pẹ̀lú òtítọ́ inú, wọ́n ń gbèrò láti fi ìpọ́njú kún ìdè mi: Àwọn kan ẹ̀wẹ̀ si ń fi ìfẹ́ ṣe é, nítorí tí wọ́n mọ̀ pé a gbé mi dìde láti dá ààbò bo iṣẹ́ ìhìnrere. Kí ló tún kù? Kìkì í pé níbi gbogbo, ìbá à ní ìfẹ̀tànṣe tàbí ni ti òtítọ́ a sá à n wàásù Kristi, èmi sì ń yọ̀ nítorí èyí. Nítòótọ́, èmi ó sì máa yọ̀