Filp 1:12-18

Filp 1:12-18 YBCV

Njẹ emi fẹ ki ẹnyin ki o mọ̀, ará, pe nkan wọnni ti o de bá mi, o kuku yọri si ilọsiwaju ihinrere; Tobẹ ti idè mi gbogbo farahan ninu Kristi larin awọn ọmọ-ogun ãfin ati gbogbo awọn ẹlomiran; Ati pe ọ̀pọlọpọ awọn arakunrin ninu Oluwa, ti o ni igbẹkẹle si ìde mi nfi igboiya gidigidi sọrọ Ọlọrun laibẹru. Nitotọ awọn ẹlomiran tilẹ nfi ija ati ilara wasu Kristi; awọn ẹlomiran si nfi inu rere ṣe e. Awọn kan nfi ìja wasu Kristi, kì iṣe pẹlu õtọ inu, nwọn ngbèro lati fi ipọnju kún ìde mi: Awọn kan ẹwẹ si nfi ifẹ ṣe e, nitoriti nwọn mọ̀ pe a gbe mi dide fun idahun-ẹjọ ihinrere. Njẹ kini? bikoṣepe nibi gbogbo, iba ṣe niti àfẹ̀tànṣe tabi niti otitọ, a sa nwasu Kristi; emi si nyọ̀ nitorina, nitõtọ, emi ó si ma yọ̀.