Filemoni Ìfáàrà
Ìfáàrà
Ìfáàrà sí ìwé Filemoni
Ẹrú kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Onesimu ní ọ̀gá kan tí ń jẹ́ Filemoni, ẹni tí í ṣe Kristiani kan ní Kolose. Ẹni tí ó sá ní ọ̀dọ̀ olówó rẹ̀ lọ sí Romu. Níbí ni ó ti gbọ́ ọ̀rọ̀ ìyìnrere láti ẹnu Paulu tí ó sì di Kristiani. Paulu kọ lẹ́tà yìí sí Filemoni kí ó lè gba Onesimu padà sí ọ̀dọ̀ gẹ́gẹ́ bí arákùnrin rẹ̀ nínú ìgbàgbọ́, kí i sì ṣe bí ẹrú tó ti jẹ́ tẹ́lẹ̀ rí. Paulu sọ pé nísinsin yìí, Onesimu yóò wúlò fún Filemoni àti fún iṣẹ́ ìyìnrere.
Ìwé kékeré yìí ṣe pàtàkì ní gbogbo ọ̀nà. Ohun méjì pàtàkì ni ó fi ara hàn nínú rẹ̀. Ní ọ̀nà kìn-ín-ní, a rí i bí ìyìnrere ṣe ń ṣiṣẹ́, kò sí ẹni tó burú kọjá iṣẹ́ Ọlọ́run tó fi dé orí ẹni tó sálọ. Bí ẹnikẹ́ni bá gba Kristi yóò di ènìyàn ọ̀tun. Ní ọ̀nà kejì ẹ̀wẹ̀, àwọn èrò tó máa ń fa ìdínà àti ìkórìíra ní ìgbà àtijọ́ ti di àmúkúrò. Filemoni àti Onesimu ti di arákùnrin kan náà nínú ìgbàgbọ́ nísinsin yìí. Ní àìpẹ́ ni gbogbo ìlànà amúnilẹ́rú yóò fọ́ túútúú nípasẹ̀ ẹ̀kọ́ Kristi.
Kókó-ọ̀rọ̀
Ìkíni 1.1-3.
Paulu gbé oríyìn fún Filemoni 4-7.
Paulu bẹ̀bẹ̀ fún Onesimu 8-22.
Ọ̀rọ̀ ìparí 23-25.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Filemoni Ìfáàrà: BMYO
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.
A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.
Yoruba Contemporary Bible
Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.
Used by permission of Biblica, Inc. All rights reserved worldwide.