Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ nípa Ninefe. Ìwé ìran Nahumu ará Elkoṣi. OLúWA Ọlọ́run ń jẹ owú, ó sì ń gbẹ̀san. OLúWA ń gbẹ̀san, ó sì kún fún ìbínú OLúWA ń gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀, Ìbínú rẹ̀ kò sì yí padà lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀ OLúWA lọ́ra láti bínú, ó sì tóbi ní agbára; OLúWA kì yóò fi àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ sílẹ̀ láìjìyà. Ọ̀nà rẹ̀ wà nínú afẹ́fẹ́ àti nínú ìjì, Ìkùùkuu sánmọ̀ sì ni eruku ẹsẹ̀ rẹ̀. Ó bá Òkun wí, ó sì mú kí ó gbẹ; Ó sìsọ gbogbo odò di gbígbẹ. Baṣani àti Karmeli sì rọ, Ìtànná Lebanoni sì rẹ̀ sílẹ̀. Àwọn òkè ńlá wárìrì níwájú rẹ̀, àwọn òkè kéékèèkéé sì di yíyọ́, ilẹ̀ ayé sì jóná níwájú rẹ̀, àní ayé àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀. Ta ni ó lé dúró níwájú ìbínú rẹ̀? Ta ni ó lé faradà gbígbóná ìbínú rẹ̀? Ìbínú rẹ̀ tú jáde bí iná; àwọn àpáta sì fọ́ túútúú níwájú rẹ̀. Rere ni OLúWA, òun ni ààbò ní ọjọ́ ìpọ́njú. Òun sì tọ́jú àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé e, Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìkún omi ńlá ní òun yóò fi ṣe ìparun láti ibẹ̀ dé òpin; òkùnkùn yóò sì máa lépa àwọn ọ̀tá rẹ̀.
Kà Nahumu 1
Feti si Nahumu 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Nahumu 1:1-8
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò