Ó sì ṣe, bí Jesu tí jókòó ti ó ń jẹun nínú ilé Matiu, sì kíyèsi i, ọ̀pọ̀ àwọn agbowó òde àti “ẹlẹ́ṣẹ̀” wá, wọ́n sì bá a jẹun pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Nígbà tí àwọn Farisi sì rí i, wọ́n wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “ ‘Èéṣe’ tí olùkọ́ yín fi ń bá àwọn agbowó òde àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹun pọ̀?” Ṣùgbọ́n nígbà tí Jesu gbọ́ èyí, ó wí fún wọn pé, “Àwọn tí ara wọ́n le kò wá oníṣègùn bí kò ṣe àwọn tí ara wọn kò dá. Ṣùgbọ́n ẹ lọ kọ́ ohun ti èyí túmọ̀ sí: ‘Àánú ni èmi ń fẹ́, kì í ṣe ẹbọ;’ nítorí èmi kò wá láti pe àwọn olódodo, bí kò ṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.” Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu tọ̀ ọ́ wá láti béèrè wí pé, “Èéṣe tí àwa àti àwọn Farisi fi ń gbààwẹ̀, ṣùgbọ́n tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ kò gbààwẹ̀?” Jesu sì dáhùn pé, “Àwọn ọmọ ilé ìyàwó ha le máa ṣọ̀fọ̀, nígbà tí ọkọ ìyàwó ń bẹ lọ́dọ̀ wọn? Ṣùgbọ́n ọjọ́ ń bọ̀ nígbà tí a ó gba ọkọ ìyàwó lọ́wọ́ wọn; nígbà náà ni wọn yóò gbààwẹ̀. “Kò sí ẹni tí ń fi ìrépé aṣọ tuntun lẹ ògbólógbòó ẹ̀wù; nítorí èyí tí a fi lẹ̀ ẹ́ yóò ya ní ojú lílẹ̀, aṣọ náà yóò sì ya púpọ̀ sì i ju ti ìṣáájú lọ. Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí fi ọtí tuntun sínú ògbólógbòó ìgò-awọ; bí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìgò-awọ yóò bẹ́, ọtí á sì tú jáde, ìgò-awọ á sì ṣègbé. Ṣùgbọ́n ọtí tuntun ni wọn í fi sínú ìgò-awọ tuntun àwọn méjèèjì a sì ṣe déédé.”
Kà Matiu 9
Feti si Matiu 9
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Matiu 9:10-17
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò