“Ẹ̀yin ti gbọ́ bí a ti wí fún àwọn ará ìgbàanì pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn, ẹnikẹ́ni tí ó bá pànìyàn yóò wà nínú ewu ìdájọ́.’ Ṣùgbọ́n èmi wí fún un yín pé, ẹnikẹ́ni tí ó bínú sí arákùnrin rẹ̀ yóò wà nínú ewu ìdájọ́. Ẹnikẹ́ni ti ó ba wí fun arákùnrin rẹ̀ pé, ‘ Ráákà ,’ yóò fi ara hàn níwájú ìgbìmọ̀ àwọn àgbà Júù; ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá wí pé, ‘Ìwọ wèrè!’ yóò wà nínú ewu iná ọ̀run àpáàdì.
“Nítorí náà, nígbà tí ìwọ bá ń mú ẹ̀bùn rẹ wá síwájú pẹpẹ, bí ìwọ bá sì rántí níbẹ̀ pé arákùnrin rẹ̀ ni ohùn kan nínú sí ọ. Fi ẹ̀bùn rẹ sílẹ̀ níwájú pẹpẹ. Ìwọ kọ́kọ́ lọ ṣe ìlàjà láàrín ìwọ àti arákùnrin rẹ̀ na. Lẹ́yìn náà, wá kí ó sì fi ẹ̀bùn rẹ sílẹ̀.
“Bá ọ̀tá rẹ làjà kánkán, ẹni tí ó ń gbé ọ lọ sílé ẹjọ́. Ṣe é nígbà ti ó wà ní ọ̀nà pẹ̀lú rẹ, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ yóò fà ọ́ lé onídàájọ́ lọ́wọ́, onídàájọ́ yóò sí fá ọ lé àwọn ẹ̀ṣọ́ lọ́wọ́, wọ́n a sì sọ ọ́ sínú túbú. Lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, ìwọ kì yóò jáde kúrò níbẹ̀ títí tí ìwọ yóò fi san ẹyọ owó kan tí ó kù.
“Ẹ̀yin ti gbọ́ bí òfin ti wí pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà.’ Ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá wo obìnrin kan ní ìwòkuwò, ti bà ṣe panṣágà nínú ọkàn rẹ̀. Bí ojú ọ̀tún rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́ jáde, kí ó sì sọ ọ́ nù. Ó sá à ní èrè fún ọ kí ẹ̀yà ara rẹ kan ṣègbé, ju kí a gbé gbogbo ara rẹ jù sí iná ọ̀run àpáàdì. Bí ọwọ́ ọ̀tún rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, gé e kúrò, kí ó sì sọ ọ́ nù. Ó sá à ní èrè kí ẹ̀yà ara rẹ kan ṣègbé ju kí a gbé gbogbo ara rẹ jù sí iná ọ̀run àpáàdì.
“A ti wí pẹ̀lú pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, jẹ́ kí ó fi ìwé ìkọ̀sílẹ̀ lé e lọ́wọ́.’ Ṣùgbọ́n èmi sọ èyí fún yín pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, láìṣe pé nítorí àgbèrè, ó mú un ṣe àgbèrè, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbé ẹni tí a kọ̀ ní ìyàwó, ó ṣe panṣágà.
“Ẹ̀yin ti gbọ́ bí a ti wí fún àwọn ará ìgbàanì pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ búra èké bí kò ṣe pé kí ìwọ kí ó mú ìbúra rẹ̀ fún Olúwa ṣẹ.’ Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín, ẹ má ṣe búra rárá: ìbá à ṣe fífi ọ̀run búra, nítorí ìtẹ́ Ọlọ́run ni. Tàbí fi ayé búra, nítorí àpótí ìtìsẹ̀ Ọlọ́run ni; tàbí Jerusalẹmu, nítorí olórí ìlú ọba Ńlá ni. Má ṣe fi orí rẹ búra, nítorí ìwọ kò lè sọ irun ẹyọ kan di funfun tàbí di dúdú. Ẹ jẹ́ kí bẹ́ẹ̀ ni yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àti bẹ́ẹ̀ kọ́ yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ kọ́, ohunkóhun tí ó ba ju ìwọ̀nyí lọ, wá láti ọ̀dọ̀ ẹni ibi.
“Ẹ̀yin tí gbọ́ bí òfin tí wí pé, ‘Ojú fún ojú àti eyín fún eyín.’ Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín pé, ẹ má ṣe tako ẹni ibi. Bí ẹnìkan bá gbá ọ lẹ́rẹ̀kẹ́ ọ̀tún, yí ẹ̀rẹ̀kẹ́ òsì sí olúwa rẹ̀ pẹ̀lú. Bí ẹnìkan bá fẹ́ gbé ọ lọ sílé ẹjọ́, tí ó sì fẹ́ gba ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀, jọ̀wọ́ agbádá rẹ fún un pẹ̀lú. Bí ẹni kan bá fẹ́ fi agbára mú ọ rìn ibùsọ̀ kan, bá a lọ ní ibùsọ̀ méjì. Fi fún ẹni tí ó béèrè lọ́wọ́ rẹ, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ń fẹ́ wín lọ́wọ́ rẹ, má ṣe mú ojú kúrò.