Matiu 5:13-20

Matiu 5:13-20 YCB

“Ẹ̀yin ni iyọ̀ ayé. Ṣùgbọ́n bí iyọ̀ bá di òbu kí ni a ó fi mú un dùn? Kò tún wúlò fún ohunkóhun mọ́, bí kò ṣe pé kí a dàánù, kí ó sì di ohun tí ènìyàn ń fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀. “Ẹyin ni ìmọ́lẹ̀ ayé. Ìlú tí a tẹ̀dó sórí òkè kò lè fi ara sin. Bẹ́ẹ̀ ni a kì í tan fìtílà tán, kí a sì gbé e sí abẹ́ òṣùwọ̀n; bí kò ṣe sí orí ọ̀pá fìtílà, a sì tan ìmọ́lẹ̀ fún gbogbo ẹni tí ń bẹ nínú ilé. Bákan náà, ẹ jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ yín kí ó mọ́lẹ̀ níwájú ènìyàn, kí wọ́n lè máa rí iṣẹ́ rere yín, kí wọn lè máa yin baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run lógo. “Ẹ má ṣe rò pé, èmí wá láti pa òfin àwọn wòlíì run, èmi kò wá láti pa wọn rẹ́, bí kò ṣe láti mú wọn ṣẹ. Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, títí ọ̀run òun ayé yóò fi kọjá, ààmì kínkínní tí a fi gègé ṣe kan kì yóò parẹ́ kúrò nínú gbogbo òfin tó wà nínú ìwé òfin títí gbogbo rẹ̀ yóò fi wá sí ìmúṣẹ. Ẹnikẹ́ni ti ó bá rú òfin tí ó tilẹ̀ kéré jùlọ, tí ó sì kọ́ ẹlòmíràn láti ṣe bẹ́ẹ̀, òun ni yóò kéré jùlọ ní ìjọba ọ̀run, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe wọ́n, tí ó sì ń kọ́ wọn, ni yóò jẹ́ ẹni ńlá ní ìjọba ọ̀run. Nítorí náà ni mo ti wí fún yín pé àfi bí òdodo yín bá ju ti àwọn Farisi àti ti àwọn olùkọ́ òfin lọ, dájúdájú ẹ̀yin kì yóò le wọ ìjọba ọ̀run.

Àwọn fídíò fún Matiu 5:13-20