Jesu sì pe ọmọ kékeré kan sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀. Ó sì mú un dúró láàrín wọn. Ó wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, àfi bí ẹ̀yin bá yí padà kí ẹ sì dàbí àwọn ọmọdé, ẹ̀yin kì yóò lè wọ ìjọba ọ̀run. Nítorí náà, ẹni tí ó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọdé yìí, ni yóò pọ̀ jùlọ ní ìjọba ọ̀run. Àti pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ọmọ kékeré bí èyí nítorí orúkọ mi, gbà mí. “Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni nínú yín tí ó bá mú ọ̀kan nínú àwọn ọmọ kékeré wọ̀nyí tí ó gbà mí gbọ́ ṣìnà, yóò sàn fún un kí a so òkúta ńlá mọ́ ọn ní ọrùn, kí a sì rì í sí ìsàlẹ̀ ibú omi Òkun.
Kà Matiu 18
Feti si Matiu 18
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Matiu 18:2-6
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò