Matiu 10:26-42

Matiu 10:26-42 YCB

“Nítorí náà, ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn, nítorí kò sí ohun tó ń bọ̀ tí kò ní í fi ara hàn, tàbí ohun tó wà ní ìkọ̀kọ̀ tí a kò ní mọ̀ ni gbangba. Ohun tí mo bá wí fún yín ní òkùnkùn, òun ni kí ẹ sọ ní ìmọ́lẹ̀. Èyí tí mo sọ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ sì etí yín ni kí ẹ kéde rẹ́ lórí òrùlé. Ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn tí ó le pa ara nìkan; ṣùgbọ́n tí wọn kò lè pa ẹ̀mí. Ẹ bẹ̀rù Ẹni tí ó le pa Ẹ̀mí àti ara run ní ọ̀run àpáàdì. Ológoṣẹ́ méjì kọ́ ni à ń tà ní owó idẹ wẹ́wẹ́ kan? Síbẹ̀ kò sí ọ̀kan nínú wọn tí yóò ṣubú lu ilẹ̀ lẹ́yìn Baba yin. Àti pé gbogbo irun orí yín ni a ti kà pé. Nítorí náà, ẹ má ṣe fòyà; ẹ̀yin ní iye lórí ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́ lọ. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́wọ́ mi níwájú ènìyàn, òun náà ni èmi yóò jẹ́wọ́ rẹ̀ níwájú Baba mi ní ọ̀run. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sẹ́ mí níwájú àwọn ènìyàn, òun náà ni èmi náà yóò sọ wí pé n kò mọ̀ níwájú Baba mi ní ọ̀run. “Ẹ má ṣe rò pé mo mú àlàáfíà wá sí ayé, Èmi kò mú àlàáfíà wá bí kò ṣe idà. Nítorí èmi wá láti ya “ ‘ọmọkùnrin ní ipa sí baba rẹ̀, ọmọbìnrin ní ipa sí ìyá rẹ̀, àti aya ọmọ sí ìyakọ rẹ̀… Ará ilé ènìyàn ni yóò sì máa ṣe ọ̀tá rẹ̀.’ “Ẹni tí ó bá fẹ́ baba rẹ̀ tàbí ìyá rẹ̀ jù mí lọ, kò yẹ ní tèmi, ẹni tí ó ba fẹ́ ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin rẹ̀ jù mí lọ, kò yẹ ní tèmi; Ẹni tí kò bá gbé àgbélébùú rẹ̀ kí ó tẹ̀lé mi kò yẹ ní tèmi. Ẹni tí ó bá wa ẹ̀mí rẹ̀ yóò sọ ọ́ nù, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sọ ẹ̀mí rẹ̀ nú nítorí tèmi ni yóò rí i. “Ẹni tí ó bá gbà yín, ó gbà mí, ẹni tí ó bá sì gbà mí gba ẹni tí ó rán mi. Ẹni tí ó ba gba wòlíì, nítorí pé ó jẹ́ wòlíì yóò jẹ èrè wòlíì, ẹni tí ó bá sì gba olódodo nítorí ti ó jẹ́ ènìyàn olódodo, yóò jẹ èrè olódodo. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ago omi tútù fún ọ̀kan nínú àwọn onírẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí mu nítorí tí ó jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, kò ní pàdánù èrè rẹ̀.”

Àwọn fídíò fún Matiu 10:26-42