Luku 3:7-18

Luku 3:7-18 BMYO

Nígbà náà ni ó wí fún ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn tí ó wá láti ṣe ìtẹ̀bọmi lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin ìran paramọ́lẹ̀, ta ni ó kìlọ̀ fún un yín láti sá kúrò nínú ìbínú tí ń bọ̀? Nítorí náà kí ẹ̀yin kí ó so èso tí ó yẹ fún ìrònúpìwàdà, kí ẹ má sì ṣe sí í wí nínú ara yín pé, ‘Àwa ní Abrahamu ní baba.’ Kí èmi kí ó wí fún un yín, Ọlọ́run lè gbé ọmọ dìde fún Abrahamu nínú òkúta wọ̀nyí. Àti nísinsin yìí pẹ̀lú, a fi àáké lé gbòǹgbò igi náà, gbogbo igi tí kò bá so èso rere, a óò ge lulẹ̀, a sì wọ jù sínú iná.” Àwọn ènìyàn sì ń bi í pé, “Kí ni kí àwa kí ó ṣe?” Ó dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ẹni tí ó bá ní ẹ̀wù méjì, kí ó fi ọ̀kan fún ẹni tí kò ní; ẹni tí ó bá sì ní oúnjẹ, kí ó ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.” Àwọn agbowó òde sì tọ̀ ọ́ wá láti ṣe ìtẹ̀bọmi lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì bi í pé, “Olùkọ́, kí ni àwa ó ha ṣe?” Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe fi agbára gbà jù bí a ti rán yín lọ mọ́.” Àwọn ọmọ-ogun sì béèrè lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Àti àwa, kí ni àwa ó ṣe?” Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe hùwà ipá sí ẹnikẹ́ni, kí ẹ má sì ṣe ka ẹ̀sùn èké sí ẹnikẹ́ni; kí òwò ọ̀yà yín tó yín.” Bí àwọn ènìyàn sì ti ń retí, tí gbogbo wọn sì ń rò nínú ara wọn nítorí Johanu, bí òun ni Kristi tàbí òun kọ́; Johanu dáhùn ó sì wí fún gbogbo wọn pé, “Lóòótọ́ ni èmi ń fi omi bamitiisi yín, ṣùgbọ́n ẹni tí ó lágbára jù mí lọ ń bọ̀, okùn bàtà ẹsẹ̀ ẹni tí èmi kò tó tú, Òun ni yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ àti iná bamitiisi yín. Ẹni tí àtẹ rẹ̀ ń bẹ ní ọwọ́ rẹ̀, láti gbá ilẹ̀ ìpakà rẹ̀ mọ́ tó tó, kí ó sì kó alikama rẹ̀ sínú àká; ṣùgbọ́n ìyàngbò ni yóò fi iná àjóòkú sun.” Johanu lo oríṣìíríṣìí ọ̀rọ̀ púpọ̀ láti gba àwọn ènìyàn níyànjú àti láti wàásù ìyìnrere fún wọn.

Àwọn fídíò fún Luku 3:7-18