Joṣua 9:6-11

Joṣua 9:6-11 YCB

Wọ́n sì tọ Joṣua lọ ní ibùdó ní Gilgali, wọ́n sì sọ fún òun àti àwọn ọkùnrin Israẹli pé, “Ìlú òkèrè ní àwọn ti wá, ẹ ṣe àdéhùn àlàáfíà pẹ̀lú wa.” Àwọn ọkùnrin Israẹli sọ fún àwọn ará Hifi pé, “Ṣùgbọ́n bóyá tòsí wa ni ẹ ń gbé. Báwo ni a ó ṣe lè ṣe àdéhùn pẹ̀lú yín?” “Ìránṣẹ́ rẹ ní àwa í ṣe.” Wọ́n sọ fún Joṣua. Ṣùgbọ́n Joṣua béèrè, “Ta ni yín àti pé níbo ni ẹ̀yin ti wá?” Wọ́n sì dáhùn pé: “Ní ilẹ̀ òkèèrè ní àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí wá, nítorí orúkọ OLúWA Ọlọ́run rẹ. Nítorí tí àwa ti gbọ́ òkìkí rẹ àti ohun gbogbo tí ó ti ṣe ní Ejibiti, àti ohun gbogbo tí ó ti ṣe sí ọba àwọn Amori méjèèje tí ń bẹ ní òkè Jordani, sí Sihoni ọba Heṣboni, àti Ogu ọba Baṣani, tí wọ́n jẹ ọba ní Aṣtarotu. Àwọn àgbàgbà wa àti gbogbo àwọn tí ń gbé ìlú wa sọ fún wa pé, ‘Ẹ mú oúnjẹ lọ́wọ́ fún ìrìnàjò yín, ẹ lọ pàdé wọn, kí ẹ sì sọ fún wọn pé, “Àwa ni ìránṣẹ́ yín, ẹ dá àdéhùn pẹ̀lú wa.” ’