Joṣua 22:5-6

Joṣua 22:5-6 YCB

Ṣùgbọ́n ẹ ṣọ́ra gidigidi láti pa àṣẹ àti òfin tí Mose ìránṣẹ́ OLúWA fi fún yin mọ́. Láti fẹ́ràn OLúWA Ọlọ́run yín, láti rìn nínú gbogbo ọ̀nà rẹ̀, láti gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ̀, láti dìímú ṣinṣin àti láti sìn ín pẹ̀lú gbogbo ọkàn yín àti gbogbo àyà yín.” Nígbà náà ni Joṣua súre fún wọn, ó sì jẹ́ kí wọn máa lọ sí ilẹ̀ wọn.