Nígbà náà ní Joṣua àti gbogbo Israẹli tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ kọjá láti Makkeda lọ sí Libina wọ́n sì kọlù ú. OLúWA sì fi ìlú náà àti ọba rẹ̀ lé Israẹli lọ́wọ́. Ìlú náà àti gbogbo àwọn ènìyàn ibẹ̀ ni Joṣua fi idà pa. Kò fi ẹnìkan sílẹ̀ ní ibẹ̀: Ó sì ṣe sí ọba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí ọba Jeriko.
Nígbà náà ni Joṣua àti gbogbo ará Israẹli, tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ kọjá láti Libina lọ sí Lakiṣi; ó sì dó tì í, ó sì kọlù ú. OLúWA sì fi Lakiṣi lé Israẹli lọ́wọ́, Joṣua sì gbà á ní ọjọ́ kejì. Ìlú náà àti gbogbo ènìyàn ibẹ̀ ní ó fi idà pa gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí Libina. Ní àkókò yìí, Horamu ọba Geseri gòkè láti ran Lakiṣi lọ́wọ́, ṣùgbọ́n Joṣua ṣẹ́gun rẹ̀ àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ títí ti kò fi ku ẹnìkan sílẹ̀.
Nígbà náà ni Joṣua àti gbogbo Israẹli tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ kọjá láti Lakiṣi lọ sí Egloni; wọ́n sì dó tì í, wọ́n sì kọlù ú. Wọ́n gbà á ní ọjọ́ náà, wọ́n sì fi ojú idà kọlù ú, wọ́n sì run gbogbo ènìyàn ibẹ̀ pátápátá, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe sí Lakiṣi.
Nígbà náà ni Joṣua àti gbogbo Israẹli ṣí láti Egloni lọ sí Hebroni, wọ́n sì kọlù ú. Wọ́n gba ìlú náà, wọ́n sì ti idà bọ̀ ọ́, pẹ̀lú ọba rẹ̀, gbogbo ìletò wọn àti gbogbo ènìyàn ibẹ̀. Wọn kò dá ẹnìkan sí. Gẹ́gẹ́ bí ti Egloni, wọ́n run un pátápátá àti gbogbo ènìyàn inú rẹ̀.
Nígbà náà ni Joṣua àti gbogbo Israẹli tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ yí padà, wọ́n sì kọlu Debiri. Wọ́n gba ìlú náà, ọba rẹ̀ àti gbogbo ìlú wọn, wọ́n sì fi idà pa wọ́n. Gbogbo ènìyàn inú rẹ̀ ni wọ́n parun pátápátá. Wọn kò sì dá ẹnìkankan sí. Wọ́n ṣe sí Debiri àti ọba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí wọn ti ṣe sí Libina àti ọba rẹ̀ àti sí Hebroni.
Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua ṣẹ́gun gbogbo agbègbè náà, ìlú òkè, gúúsù, ìlú ẹsẹ̀ òkè ti ìhà ìwọ̀-oòrùn àti gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè pẹ̀lú gbogbo ọba, wọn kò dá ẹnìkankan sí. Ó pa gbogbo ohun alààyè run pátápátá, gẹ́gẹ́ bí OLúWA Ọlọ́run Israẹli, ti pàṣẹ. Joṣua sì ṣẹ́gun wọn láti Kadeṣi-Barnea sí Gasa àti láti gbogbo agbègbè Goṣeni lọ sí Gibeoni. Gbogbo àwọn ọba wọ̀nyí àti ilẹ̀ wọn ní Joṣua ṣẹ́gun ní ìwọ́de ogun ẹ̀ẹ̀kan, nítorí tí OLúWA, Ọlọ́run Israẹli, jà fún Israẹli.
Nígbà náà ni Joṣua padà sí ibùdó ní Gilgali pẹ̀lú gbogbo Israẹli.