Ní báyìí tí Adoni-Sedeki ọba Jerusalẹmu gbọ́ pé Joṣua ti gba Ai, tí ó sì ti pa wọ́n pátápátá; tí ó sì ṣe sí Ai àti ọba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí Jeriko àti ọba rẹ̀, àti bí àwọn ènìyàn Gibeoni ti ṣe àdéhùn àlàáfíà pẹ̀lú Israẹli, tí wọ́n sì ń gbé nítòsí wọn. Ìbẹ̀rù sì mú òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ torí pé Gibeoni jẹ́ ìlú tí ó ṣe pàtàkì, bí ọ̀kan nínú àwọn ìlú ọba; ó tóbi ju Ai lọ, gbogbo ọkùnrin rẹ̀ ní ó jẹ́ jagunjagun. Nítorí náà Adoni-Sedeki ọba Jerusalẹmu bẹ Hohamu ọba Hebroni, Piramu ọba Jarmatu, Jafia ọba Lakiṣi àti Debiri ọba Egloni. Wí pe, “Ẹ gòkè wá, kí ẹ sì ràn mi lọ́wọ́ láti kọlu Gibeoni, nítorí tí ó ti wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Joṣua àti àwọn ará Israẹli.”
Àwọn ọba Amori márààrún, ọba Jerusalẹmu, Hebroni, Jarmatu, Lakiṣi àti Egloni, kó ara wọn jọ, wọ́n sì gòkè, àwọn àti gbogbo ogun wọn, wọ́n sì dojúkọ Gibeoni, wọ́n sì kọlù ú.
Àwọn ará Gibeoni sì ránṣẹ́ sí Joṣua ní ibùdó ní Gilgali pé: “Ẹ má ṣe fi ìránṣẹ́ yín sílẹ̀. Ẹ gòkè tọ̀ wà wá ní kánkán kí ẹ sì gbà wá là. Ẹ ràn wá lọ́wọ́, nítorí gbogbo àwọn ọba Amori tí ń gbé ní orílẹ̀-èdè òkè dojú ìjà kọ wá.”
Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua gòkè lọ láti Gilgali pẹ̀lú gbogbo ogun rẹ̀, àti akọni nínú àwọn ọmọ-ogun rẹ̀. OLúWA sì sọ fún Joṣua pé, “Má ṣe bẹ̀rù wọn; Mo ti fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́. Kò sí ẹnikẹ́ni nínú wọn ti yóò lè dojúkọ ọ́.”
Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti wọ́de ogun ní gbogbo òru náà láti Gilgali, Joṣua sì yọ sí wọn lójijì. OLúWA mú kí wọn dààmú níwájú àwọn Israẹli, wọ́n sì pa wọ́n ní ìpakúpa ní Gibeoni. Israẹli sì lépa wọn ní ọ̀nà tí ó lọ sí Beti-Horoni, ó sì pa wọ́n dé Aseka, àti Makkeda. Bí wọ́n sì tí ń sá ní iwájú Israẹli ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ ní ọ̀nà láti Beti-Horoni títí dé Aseka, OLúWA rọ yìnyín ńlá sí wọn láti ọ̀run wá, àwọn tí ó ti ipa yìnyín kú sì pọ̀ ju àwọn tí àwọn ará Israẹli fi idà pa lọ.
Ní ọjọ́ tí OLúWA fi àwọn ọmọ Amori lé Israẹli lọ́wọ́, Joṣua sọ fún OLúWA níwájú àwọn ará Israẹli:
“Ìwọ oòrùn, dúró jẹ́ẹ́ ní orí Gibeoni,
Ìwọ òṣùpá, dúró jẹ́ẹ́ lórí Àfonífojì Aijaloni.”
Bẹ́ẹ̀ ni oòrùn náà sì dúró jẹ́ẹ́,
òṣùpá náà sì dúró,
títí tí ìlú náà fi gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀,
gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ nínú ìwé Jaṣari.
Oòrùn sì dúró ní agbede-méjì ọ̀run, kò sì wọ̀ ní ìwọ̀n odindi ọjọ́ kan. Kò sí ọjọ́ tí o dàbí rẹ̀ ṣáájú tàbí ní ẹ̀yìn rẹ̀, ọjọ́ tí OLúWA gbọ́ ohùn ènìyàn. Dájúdájú OLúWA jà fún Israẹli!
Nígbà náà ni Joṣua àti gbogbo Israẹli padà sí ibùdó ní Gilgali.