Joẹli 2:1-11

Joẹli 2:1-11 YCB

Ẹ fun ìpè ní Sioni, ẹ sì fún ìpè ìdágìrì ní òkè mímọ́ mi. Jẹ́ kí àwọn ará ilẹ̀ náà wárìrì, nítorí tí ọjọ́ OLúWA ń bọ̀ wá, nítorí ó kù sí dẹ̀dẹ̀. Ọjọ́ òkùnkùn àti ìrọ́kẹ̀kẹ̀, ọjọ́ ìkùùkuu àti òkùnkùn biribiri, Bí ọyẹ́ òwúrọ̀ ti í la bo orí àwọn òkè ńlá: àwọn ènìyàn ńlá àti alágbára; ya dé, ti kó ti ì sí irú rẹ̀ rí, bẹ́ẹ̀ ni irú rẹ̀ kì yóò sí mọ́ lẹ́yìn rẹ̀, títí dé ọdún ìran dé ìran. Iná ń jó níwájú wọ́n; ọwọ́ iná sì ń jó lẹ́yìn wọn: Ilẹ̀ náà dàbí ọgbà Edeni níwájú wọn, àti lẹ́yìn wọn bí ahoro ijù; nítòótọ́, kò sì sí ohun tí yóò bọ́ lọ́wọ́ wọn. Ìrí wọn dàbí ìrí àwọn ẹṣin; wọ́n ń sáré lọ bí àwọn ẹlẹ́ṣin ogun Bí ariwo kẹ̀kẹ́ ogun ni wọn ń fo ní orí òkè bí ariwo ọ̀wọ́-iná tí ń jó koríko gbígbẹ, bí akọni ènìyàn tí a kójọ fún ogun. Ní ojú wọn, àwọn ènìyàn yóò jẹ ìrora púpọ̀: gbogbo ojú ní yóò ṣú dudu. Wọn yóò sáré bi àwọn alágbára; wọn yóò gùn odi bí ọkùnrin ológun; olúkúlùkù wọn yóò sì rìn lọ ní ọ̀nà rẹ̀, wọn kì yóò sì yà kúrò ni ọ̀nà wọn. Bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kì yóò kọlu ẹnìkejì rẹ̀; olúkúlùkù wọn yóò rìn ní ọ̀nà rẹ̀: nígbà tí wọn bá sì ṣubú lù idà wọn kì yóò gbọgbẹ́. Wọn yóò sáré síwá sẹ́yìn ní ìlú; wọn yóò súré lórí odi, wọn yóò gùn orí ilé; wọn yóò gbà ojú fèrèsé wọ̀ inú ilé bí olè. Ayé yóò mì níwájú wọn; àwọn ọ̀run yóò wárìrì; oòrùn àti òṣùpá yóò ṣókùnkùn, àwọn ìràwọ̀ yóò sì fà ìmọ́lẹ̀ wọn sẹ́yìn. OLúWA yóò sì bú ramúramù jáde níwájú ogun rẹ̀: nítorí ibùdó rẹ̀ tóbi gidigidi; nítorí alágbára ní òun, tí n mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ; nítorí ọjọ́ OLúWA tóbi ó sì ní ẹ̀rù gidigidi; ara ta ni ó lè gbà á?