Ẹ fun fèrè ní Sioni, ẹ kéde ìdágìrì lórí òkè mímọ́ mi. Kí gbogbo àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ náà wárìrì, nítorí ọjọ́ OLUWA ń bọ̀, ó sì ti dé tán. Yóo jẹ́ ọjọ́ òkùnkùn ati ìbànújẹ́, ọjọ́ ìkùukùu ati òkùnkùn biribiri. Àwọn ọmọ ogun yóo bo gbogbo òkè ńlá, bí ìgbà tí òkùnkùn bá ń ṣú bọ̀. Irú rẹ̀ kò ṣẹlẹ̀ rí ní ìgbà àtijọ́, bẹ́ẹ̀ ni irú rẹ̀ kò sì tún ní ṣẹlẹ̀ mọ́ títí lae. Iná ń jó àjórun níwájú wọn, ahọ́n iná ń yọ lálá lẹ́yìn wọn. Ilẹ̀ náà dàbí ọgbà Edẹni níwájú wọn, ṣugbọn lẹ́yìn wọn, ó dàbí aṣálẹ̀ tí ó ti di ahoro, kò sì sí ohun tí yóo bọ́ lọ́wọ́ wọn. Ìrísí wọn dàbí ìrísí ẹṣin, wọ́n sì ń sáré bí ẹṣin tí ń lọ ojú ogun. Ìró wọn dàbí ìró kẹ̀kẹ́ ogun, wọ́n ń bẹ́ lórí àwọn òkè ńlá. Ìró wọn dàbí ìró iná tí ń jó pápá, bí ìgbà tí àwọn alágbára ọmọ ogun múra fún ogun. Ìdààmú bá àwọn orílẹ̀-èdè tí ó bá ti fojú kàn wọ́n, gbogbo ọkàn á rẹ̀wẹ̀sì. Wọ́n ń sáré bí akọni, wọ́n ń fo ògiri bí ọmọ ogun. Wọ́n tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́, ẹnikẹ́ni kò sì yà kúrò ní ọ̀nà tirẹ̀. Wọn kò fi ara gbún ara wọn, olukuluku ń lọ ní ọ̀nà tirẹ̀; wọ́n kọlu àwọn nǹkan ààbò láìní ìdádúró. Wọ́n ń gun odi ìlú, wọ́n ń sáré lórí odi. Wọ́n ń gun orí ilé wọlé, wọ́n gba ojú fèrèsé bẹ́ sinu ọ̀dẹ̀dẹ̀ bí olè. Ilẹ̀ ń mì tìtì níwájú wọn, ọ̀run sì ń wárìrì, oòrùn, òṣùpá ati àwọn ìràwọ̀ ṣókùnkùn. OLUWA sọ̀rọ̀ níwájú àwọn ọmọ ogun rẹ̀, nítorí àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pọ̀ lọpọlọpọ, alágbára ni ẹni tí ń mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ. Ọjọ́ ńlá ati ọjọ́ ẹ̀rù ni ọjọ́ OLUWA! Ta ló lè faradà á?
Kà JOẸLI 2
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: JOẸLI 2:1-11
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò