Jobu 9:14-31

Jobu 9:14-31 YCB

“Kí ní ṣe tí èmi ti n o fi ba ṣàròyé? Tí èmi yóò fi ma ṣe àwáwí? Bí ó tilẹ̀ ṣe pé mo ṣe aláìlẹ́bi, èmi kò gbọdọ̀ dá a lóhùn; ṣùgbọ́n èmi ó gbàdúrà fún àánú. Bí èmi bá sì ké pè é, tí Òun sì dá mi lóhùn, èmi kì yóò sì gbàgbọ́ pé, Òun ti fetí sí ohùn mi. Nítorí pé òun yóò lọ̀ mí lúúlúú pẹ̀lú ìjì ńlá, ó sọ ọgbẹ́ mi di púpọ̀ láìnídìí. Òun kì yóò jẹ́ kí èmi kí ó rí ẹ̀mí mi, ṣùgbọ́n ó mú ohun kíkorò kún un fún mi. Bí mo bá sọ ti agbára, wò ó! Alágbára ni, tàbí ní ti ìdájọ́, ta ni yóò dá àkókò fún mi láti rò? Bí mo tilẹ̀ dá ara mi láre, ẹnu ara mi yóò dá mi lẹ́bi; bí mo wí pé olódodo ni èmi yóò sì fi mí hàn ní ẹni ẹ̀bi. “Olóòótọ́ ni mo ṣe, síbẹ̀ èmi kò kíyèsi ara mi, ayé mi ní èmi ìbá máa gàn. Ohùn kan náà ni, nítorí náà ni èmi ṣe sọ: ‘Òun a pa ẹni òtítọ́ àti ènìyàn búburú pẹ̀lú.’ Bí ìjàǹbá bá pa ni lójijì, yóò rẹ́rìn-ín nínú ìdààmú aláìṣẹ̀. Nígbà tí a bá fi ayé lé ọwọ́ ènìyàn búburú; ó sì bo àwọn onídàájọ́ rẹ̀ lójú; bí kò bá rí bẹ́ẹ̀ ǹjẹ́ ta ni? “Ǹjẹ́ nísinsin yìí ọjọ́ mi yára ju oníṣẹ́ lọ, wọ́n fò lọ, wọn kò rí ayọ̀. Wọ́n kọjá lọ bí ọkọ̀ eèsún papirusi tí ń sáré lọ; bí idì tí ń yára si ohùn ọdẹ. Bí èmi bá wí pé, ‘Èmi ó gbàgbé arò ìbìnújẹ́ mi, èmi ó fi ọkàn lélẹ̀, èmi ó sì rẹ ara mi lẹ́kún.’ Ẹ̀rù ìbànújẹ́ mi gbogbo bà mí, èmi mọ̀ pé ìwọ kì yóò mú mi bí aláìṣẹ̀. Bí ó bá ṣe pé ènìyàn búburú ni èmi, ǹjẹ́ kí ni èmi ń ṣe làálàá lásán sí? Bí mo tilẹ̀ fi ọṣẹ dídì wẹ ara mi, tí mo fi omi aró wẹ ọwọ́ mi mọ́, síbẹ̀ ìwọ ó gbé mi wọ inú ihò ọ̀gọ̀dọ̀ aṣọ ara mi yóò sọ mi di ìríra.