“Ó mú àwọn arákùnrin mi jìnà sí mi réré, àti àwọn ojúlùmọ̀ mi di àjèjì sí mi pátápátá. Àwọn alájọbí mi fàsẹ́yìn, àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ mi sì di onígbàgbé mi. Àwọn ará inú ilé mi àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin mi kà mí sí àjèjì; èmi jásí àjèjì ènìyàn ní ojú wọn. Mo pe ìránṣẹ́ mi, òun kò sì dá mi lóhùn; mo fi ẹnu mi bẹ̀ ẹ́. Ẹ̀mí mi ṣú àyà mi, àti òórùn mi ṣú àwọn ọmọ inú ìyá mi. Àní àwọn ọmọdékùnrin fi mí ṣẹ̀sín: Mo dìde, wọ́n sì sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí mi. Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ kòríkòsùn mi kórìíra mi, àwọn olùfẹ́ mi sì kẹ̀yìndà mí. Egungun mi lẹ̀ mọ́ ara mi àti mọ́ ẹran-ara mi, mo sì yọ́ pẹ̀lú awọ eyín mi. “Ẹ ṣàánú fún mi, ẹ ṣàánú fún mi, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, nítorí ọwọ́ Ọlọ́run ti bà mí. Nítorí kí ni ẹ̀yin ṣe lépa mi bí Ọlọ́run, tí ẹran-ara mi kò tẹ́ yín lọ́rùn? “Háà! Ìbá ṣe pé a le kọ̀wé ọ̀rọ̀ mi nísinsin yìí, ìbá ṣe pé a le kọ ọ sínú ìwé! Kí a fi kálámù irin àti ti òjé kọ wọ́n sínú àpáta fún láéláé. Nítorí èmi mọ̀ pé olùdáǹdè mi ń bẹ láààyè àti pe òun ni yóò dìde dúró lórí ilẹ̀ ní ìkẹyìn; Àti lẹ́yìn ìgbà tí a pa àwọ̀ ara mi run, síbẹ̀ láìsí ẹran-ara mi ni èmi ó rí Ọlọ́run, Ẹni tí èmi ó rí fún ara mi, tí ojú mi ó sì wo, kì sì í ṣe ti ẹlòmíràn; ọkàn mi sì dákú ní inú mi. “Bí ẹ̀yin bá wí pé, ‘àwa ó ti lépa rẹ̀ tó! Àti pé, gbogbo ọ̀rọ̀ náà ni a sá à rí ní ọwọ́ rẹ̀,’ Kí ẹ̀yin kí ó bẹ̀rù; nítorí ìbínú ní í mú ìjìyà wá nípa idà, Kí ẹ̀yin kí ó lè mọ̀ pé ìdájọ́ kan ń bẹ.”
Kà Jobu 19
Feti si Jobu 19
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Jobu 19:13-29
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò