Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá ń mú olú òfin nì ṣẹ gẹ́gẹ́ bí Ìwé mímọ́, èyí tí ó wí pé, “Ìwọ fẹ́ ẹni kejì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ,” ẹ̀yin ń ṣe dáradára. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá ń ṣe ojúsàájú ènìyàn, ẹ̀yin ń dẹ́ṣẹ̀, a sì ń dá yín lẹ́bi nípa òfin bí arúfin. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá pa gbogbo òfin mọ́, tí ó sì rú ọ̀kan, ó jẹ̀bi rírú gbogbo rẹ̀. Nítorí ẹni tí ó wí pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà,” òun ni ó sì wí pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn.” Ǹjẹ́ bí ìwọ kò ṣe panṣágà, ṣùgbọ́n tí ìwọ pànìyàn, ìwọ jásí arúfin. Ẹ máa sọ̀rọ̀, ẹ sì máa hùwà, bí àwọn tí a ó fi òfin òmìnira dá lẹ́jọ́.
Kà Jakọbu 2
Feti si Jakọbu 2
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Jakọbu 2:8-12
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò