Jakọbu 2:16-26

Jakọbu 2:16-26 YCB

Tí ẹni kan nínú yín sì wí fún pé, “Máa lọ ní àlàáfíà, kí ara rẹ kí ó má ṣe tutù, kí ó sì yó,” ṣùgbọ́n ẹ kò fi nǹkan wọ̀n-ọn-nì ti ara ń fẹ́ fún wọn; èrè kí ni ó jẹ́? Bẹ́ẹ̀ sì ni ìgbàgbọ́, bí kò bá ní iṣẹ́ rere, ó kú nínú ara rẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹnìkan lè wí pé, “Ìwọ ní ìgbàgbọ́, èmi sì ní iṣẹ́:” Fi ìgbàgbọ́ rẹ hàn mí ní àìsí iṣẹ́, èmi ó sì fi ìgbàgbọ́ mi hàn ọ́ nípa iṣẹ́ rere mi. Ìwọ gbàgbọ́ pé Ọlọ́run kan ní ó ń bẹ; ó dára! Àwọn ẹ̀mí èṣù pẹ̀lú gbàgbọ́ bẹ́ẹ̀, wọ́n sì wárìrì. Ṣùgbọ́n, ìwọ aláìmòye ènìyàn, ìwọ ha fẹ́ ní ìdánilójú pé, ìgbàgbọ́ ní àìsí iṣẹ́ rere asán ni? Kí ha í ṣe nípa iṣẹ́ ni a dá Abrahamu baba wa láre, nígbà tí ó fi Isaaki ọmọ rẹ̀ rú ẹbọ lórí pẹpẹ? Ìwọ rí i pé ìgbàgbọ́ rẹ bá iṣẹ́ rìn, àti pé nípa iṣẹ́ rere ni a sọ ìgbàgbọ́ di pípé. Ìwé Mímọ́ sì ṣẹ́ tí ó wí pé, “Abrahamu gba Ọlọ́run gbọ́, a sì kà á sí òdodo fún un,” a sì pè é ní ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Ǹjẹ́ ẹ̀yin rí i pé nípa iṣẹ́ rere ni à ń dá ènìyàn láre, kì í ṣe nípa ìgbàgbọ́ nìkan. Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú kí a dá Rahabu panṣágà láre nípa iṣẹ́ bí, nígbà tí ó gba àwọn ayọ́lẹ̀wò, tí ó sì rán wọn jáde gba ọ̀nà mìíràn? Nítorí bí ara ní àìsí ẹ̀mí ti jẹ́ òkú, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ pẹ̀lú ni ìgbàgbọ́ ní àìsí iṣẹ́ jẹ́ òkú.