Jakọbu 1:18-22

Jakọbu 1:18-22 YCB

Ó pinnu láti fi ọ̀rọ̀ òtítọ́ bí wa kí àwa kí ó le jẹ́ àkọ́so nínú ohun gbogbo tí ó dá. Kí ẹ mọ èyí, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́; jẹ́ kí olúkúlùkù ènìyàn kí ó máa yára láti gbọ́, kí ó lọ́ra láti fọhùn, kí ó si lọ́ra láti bínú; Nítorí ìbínú ènìyàn kì í ṣiṣẹ́ òdodo irú èyí tí Ọlọ́run ń fẹ́. Nítorí náà, ẹ lépa láti borí gbogbo èérí àti ìwà búburú tí ó gbilẹ̀ yíká, kí ẹ sì fi ọkàn tútù gba ọ̀rọ̀ náà tí a gbìn, tí ó lè gba ọkàn yín là. Ẹ má kan jẹ́ olùgbọ́ ọ̀rọ̀ náà lásán, kí ẹ má ba à ti ipa èyí tan ara yín jẹ́. Ẹ ṣe ohun tí ó sọ.