Heberu 9:16-28

Heberu 9:16-28 BMYO

Nítorí níbi tí ìwé ogún bá gbé wà, ikú ẹni tí o ṣe é kò lè ṣe àìsí pẹ̀lú; nítorí ìwé ogún ní agbára lẹ́yìn ìgbà tí ènìyàn bá kú, nítorí kò ní agbára rárá nígbà tí ẹni tí o ṣè e bá ń bẹ láààyè. Nítorí náà ni a kò ṣe ya májẹ̀mú ìṣáájú pàápàá sí mímọ́ láìsí ẹ̀jẹ̀. Nítorí nígbà tí Mose ti sọ gbogbo àṣẹ nípa ti òfin fún gbogbo àwọn ènìyàn, ó mú ẹ̀jẹ̀ ọmọ màlúù àti ti ewúrẹ́, pẹ̀lú omi, àti òwú òdòdó, àti ewé hísópù ó sì fi wọ́n àti ìwé pàápàá àti gbogbo ènìyàn. Wí pé, “Èyí ní ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú tí Ọlọ́run pàṣẹ fún yín.” Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ó sì fi ẹ̀jẹ̀ wọ́n àgọ́, àti gbogbo ohun èlò ìsìn. Ó sì fẹ́rẹ̀ jẹ́ ohun gbogbo ni a fi ẹ̀jẹ̀ wẹ̀nù gẹ́gẹ́ bí òfin; àti pé láìsí ìtàjẹ̀ sílẹ̀ kò sí ìdáríjì. Nítorí náà a kò lè ṣàì fi ìwọ̀nyí wé àwọn àpẹẹrẹ ohun tí ń bẹ lọ́run mọ́; ṣùgbọ́n ó yẹ kí a fi ẹbọ tí ó sàn ju ìwọ̀nyí lọ wẹ àwọn ohun ọ̀run pàápàá mọ́; ṣùgbọ́n ó yẹ kí a fi ẹbọ tí ó sàn ju ìwọ̀nyí lọ wẹ àwọn ohun ọ̀run pàápàá mọ́. Nítorí Kristi kò wọ ibi mímọ́ tí a fi ọwọ́ ṣe lọ tí i ṣe àpẹẹrẹ ti òtítọ́; ṣùgbọ́n ó lọ sí ọ̀run pàápàá, nísinsin yìí láti farahàn ní iwájú Ọlọ́run fún wa. Kì í sí i ṣe pé kí ó lè máa fi ara rẹ̀ rú ẹbọ nígbàkígbà, bí olórí àlùfáà tí máa ń wọ inú Ibi Mímọ́ Jùlọ lọ lọ́dọọdún ti òun pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ ti kì í ṣe tirẹ̀, bí bẹ́ẹ̀ bá ni, òun ìbá tí máa jìyà nígbàkígbà láti ìpìlẹ̀ ayé. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ni ó fi ara hàn lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo lópin ayé láti mu ẹ̀ṣẹ̀ kúrò nípa ẹbọ ara rẹ̀. Níwọ́n bí a sì ti fi lélẹ̀ fún gbogbo ènìyàn láti kú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, ṣùgbọ́n lẹ́yìn èyí ìdájọ́, bẹ́ẹ̀ ni Kristi pẹ̀lú lẹ́yìn tí a ti fi rú ẹbọ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láti ru ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀, yóò farahàn ní ìgbà kejì láìsí ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn tí n wo ọ̀nà rẹ̀ fún ìgbàlà.