Esekiẹli Ìfáàrà

Ìfáàrà
Esekiẹli jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Júù tí Nebukadnessari kó ní ìgbèkùn lọ sí Babeli. Nígbà tí ó wà ní ìgbèkùn ní àárín àwọn ènìyàn ni ó gbọ́ ìpè rẹ̀ láti di wòlíì. Ó wá láti ìdílé àlùfáà, nítorí náà ó ní ẹ̀tọ́ láti ṣe iṣẹ́ ẹ̀sìn àlùfáà. Ó kún fún ìmọ̀ ìjìnlẹ̀. Òun gẹ́gẹ́ bí wòlíì àti àlùfáà tí a pè fún iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn ìgbèkùn, àní àwọn tí a gé kúrò láti sìn ni tẹmpili. Ọ̀rọ̀ ìyànjú rẹ̀ ní í ṣe púpọ̀ pẹ̀lú tẹmpili. Ní ọdún méje àkọ́kọ́ iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀, ó fi òtítọ́ sọ fún àwọn Júù ará rẹ̀ tí ó burú, tí ọkàn wọn kò dúró, tí wọn kò ní ìrètí nínú ìdájọ́ Ọlọ́run pé: Jerusalẹmu yóò ṣubú, bẹ́ẹ̀ ni a kò ní tìtorí pé wọ́n jẹ́ ẹni májẹ̀mú Ọlọ́run, tàbí pé Jerusalẹmu jẹ́ ibùgbé tẹmpili dá wọn ní ìdè ní ìgbèkùn.
Lẹ́yìn ìgbà tí Olúwa ti sọ di mí mọ̀ pé Jerusalẹmu ti wà ní abẹ́ ìbáwí àti pé yóò ṣubú, ni a ti sọ fún Esekiẹli pé ìyàwó rẹ̀ tí ó fẹ́ jùlọ yóò kú ní àìpẹ́. A ó mú ohun tí ó ń fún un ní ayọ̀ kúrò gẹ́gẹ́ bí a ti mú tẹmpili kúrò, a ó sì mú ohun tó jẹ́ àrídunnú Israẹli kúrò. Kò sì gbọdọ̀ sọkún ní gbangba nítorí aya rẹ̀, bí àwọn ènìyàn rẹ̀ kò ṣe gbọdọ̀ sọkún lórí Jerusalẹmu. A sì pa á láṣẹ láti sọ nípa àwọn ibi tí yóò wá sí orí àwọn orílẹ̀-èdè Ammoni, Moabu, Edomu, Filistia, Tire, Sidoni àti Ejibiti. Ọjọ́ ìbínú Olúwa súnmọ́ etílé, ṣùgbọ́n kì í ṣe lórí Israẹli nìkan. Ìsọjí, ìrètí àti ọjọ́ iwájú tó ní ògo yóò sì padà dé.
Mímọ́ àti títóbi Ọlọ́run ní ó tẹnumọ́ púpọ̀. “Wọn yóò sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa” fi èrò Ọlọ́run hàn. Ó sọ ìfarahàn Ọlọ́run nípa ìṣubú Jerusalẹmu àti wíwó tẹmpili. Gbogbo orílẹ̀-èdè ni yóò mọ Ọlọ́run nípa ìdájọ́ rẹ̀. Ìtọ́kasí Esekiẹli nípa “Ọmọ ènìyàn” sọ ọ̀rọ̀ ìmọ́kànle fún Israẹli nítorí gbogbo ìlérí Ọlọ́run ni yóò wá sí ìmúṣẹ nípa mí mọ̀ títóbi rẹ̀.
Kókó-ọ̀rọ̀:
i. Ìdájọ́ Ọlọ́run lórí Israẹli 1–24.
ii. Ìsọtẹ́lẹ̀ àti ìkìlọ̀ Ọlọ́run lórí àwọn orílẹ̀-èdè 25–32.
iii. Ọ̀rọ̀ ìmọ́kànle fún Israẹli 33–39.
iv. tẹmpili àti àyíká rẹ̀ 40–44.
v. Pínpín ilẹ̀ náà 45–48.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Esekiẹli Ìfáàrà: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa