Lẹ́yìn náà ni Mose àti Aaroni tọ Farao lọ, wọ́n sì wí pé, “Èyí ni ohun tí OLúWA, Ọlọ́run Israẹli sọ: ‘Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn kí ó lè ṣe àjọ mi ní ijù.’ ” Farao dáhùn wí pé, “Ta ni OLúWA, tí èmi yóò fi gbọ́rọ̀ sí i lẹ́nu, tí èmi yóò fi jẹ́ kí Israẹli ó lọ? Èmi kò mọ OLúWA, èmi kò sì ní jẹ́ kí Israẹli ó lọ.” Lẹ́yìn náà ni wọ́n wí pé, “Ọlọ́run àwọn Heberu tí pàdé wa. Ní ìsinsin yìí, jẹ́ kí a lọ ní ìrìn ọjọ́ mẹ́ta sínú aginjù láti rú ẹbọ sí OLúWA Ọlọ́run wa, kí Ó má ba á fi àjàkálẹ̀-ààrùn tàbí idà bá wa jà.” Ṣùgbọ́n ọba Ejibiti sọ wí pé, “Mose àti Aaroni, èéṣe ti ẹ̀yin fi mú àwọn ènìyàn kúrò lẹ́nu iṣẹ́ wọn? Ẹ padà sẹ́nu iṣẹ́ yín.” Nígbà náà ni Farao sọ pé, “Ẹ wò ó àwọn ènìyàn náà ti pọ̀ sí ì nílẹ̀ yìí ní ìsinsin yìí, ẹ̀yin sì ń dá wọn dúró láti máa bá iṣẹ́ lọ.”
Kà Eksodu 5
Feti si Eksodu 5
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Eksodu 5:1-5
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò