Efesu 4:21-32

Efesu 4:21-32 YCB

Bí ó bá ṣe pé nítòótọ́ ni ẹ ti gbóhùn rẹ̀ ti a sì ti kọ́ yín nínú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí òtítọ́ ti ń bẹ nínú Jesu. Pé, ní tì ìwà yín àtijọ́, kí ẹ̀yin bọ́ ògbólógbòó ọkùnrin nì sílẹ̀, èyí tí ó díbàjẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ẹ̀tàn; Kí ẹ sì di tuntun ni ẹ̀mí inú yín; kí ẹ sì gbé ọkùnrin tuntun ni wọ̀, èyí tí a dá ni àwòrán Ọlọ́run nínú òdodo àti ìwà mímọ́ ti òtítọ́. Nítorí náà ẹ fi èké ṣíṣe sílẹ̀, ki olúkúlùkù yín kí ó máa ba ọmọnìkejì rẹ̀ sọ òtítọ́, nítorí ẹ̀yà ara ọmọnìkejì wa ni àwa jẹ́. Nínú ìbínú yín, ẹ máa ṣe ṣẹ̀, ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá ìbínú yín: Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe fi ààyè ẹ̀gbẹ́ kan fún Èṣù. Kí ẹni tí ń jalè má ṣe jalè mọ́: ṣùgbọ́n kí ó kúkú máa ṣe làálàá, kí ó máa fi ọwọ́ rẹ̀ ṣiṣẹ́ ohun tí ó dára, kí òun lè ní láti pín fún ẹni tí ó ṣe aláìní. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìdíbàjẹ́ kan ti ẹnu yín jáde, ṣùgbọ́n irú èyí tí ó lè ràn ìdàgbàsókè wọn lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí ohun tí wọ́n nílò, kí ó lè máa fi oore-ọ̀fẹ́ fún àwọn tí ń gbọ́. Ẹ má sì ṣe mú Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọ́run bínú, ẹni tí a fi ṣe èdìdì yín dé ọjọ́ ìdáǹdè. Gbogbo ìwà kíkorò àti ìbínú, àti ìrunú, àti ariwo, àti ọ̀rọ̀ búburú ni kí a mú kúrò lọ́dọ̀ yín, pẹ̀lú gbogbo àrankàn: Ẹ máa ṣoore fún ọmọnìkejì yín, ẹ ní ìyọ́nú, ẹ máa dáríjì ara yín, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run nínú Kristi ti dáríjì yín.