Oniwaasu 7:1-13

Oniwaasu 7:1-13 YCB

Orúkọ rere sàn ju ìpara olóòórùn dídùn lọ ọjọ́ ikú sì dára ju ọjọ́ tí a bí ènìyàn lọ Ó dára láti lọ sí ilé ọ̀fọ̀ ju ibi àsè nítorí pé ikú jẹ́ àyànmọ́ gbogbo ènìyàn kí alààyè ní èyí ní ọkàn. Ìbànújẹ́ dára ju ẹ̀rín lọ, ó le è mú kí ojú rẹ̀ dàrú, ṣùgbọ́n yóò jẹ́ kí àyà rẹ le. Ọkàn ọlọ́gbọ́n wà ní ilé ọ̀fọ̀, ṣùgbọ́n ọkàn òmùgọ̀ ní ilé àríyá. Ó dára láti gba ìbáwí ọlọ́gbọ́n, ju fífetísílẹ̀ sí orin òmùgọ̀ lọ. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gún ti ń dún lábẹ́ ìkòkò ni ẹ̀rín òmùgọ̀, Asán sì ni eléyìí pẹ̀lú. Ìrẹ́jẹ a máa sọ ọlọ́gbọ́n di òmùgọ̀, àbẹ̀tẹ́lẹ̀ sì máa ń ba ìwà jẹ́ ni. Òpin ọ̀rọ̀ dára ju ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ lọ, sùúrù sì dára ju ìgbéraga lọ. Má ṣe yára bínú ní ọkàn rẹ nítorí pé orí ẹsẹ̀ òmùgọ̀ ni ìbínú ń gbé. Má ṣe sọ wí pé, “Kí ni ìdí tí àtijọ́ fi dára ju èyí?” Nítorí pé, kò mú ọgbọ́n wá láti béèrè irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀. Ọgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ogún ìní jẹ́ ohun tí ó dára ó sì ṣe àwọn tí ó rí oòrùn láǹfààní. Ọgbọ́n jẹ́ ààbò gẹ́gẹ́ bí owó ti jẹ́ ààbò ṣùgbọ́n àǹfààní òye ni èyí pé ọgbọ́n a máa tọ́jú ẹ̀mí ẹni tí ó bá ní. Wo ohun tí Ọlọ́run ti ṣe: “Ta ni ó le è to ohun tí ó ti ṣe ní wíwọ́?”