Daniẹli 11:2-20

Daniẹli 11:2-20 BMYO

“Ní ìsinsin yìí, mo sọ òtítọ́ fún ọ ọba mẹ́ta yóò dìde sí i ní Persia, àti ẹ̀kẹrin tí yóò jẹ́ ọlọ́rọ̀ ju gbogbo wọn lọ. Tí ó bá ti di alágbára nípa ọrọ̀ rẹ̀, yóò sì ru gbogbo wọn sókè lòdì sí ìjọba Giriki. Nígbà náà ni ọba alágbára kan yóò fi ara hàn, yóò ṣe àkóso pẹ̀lú agbára ńlá, yóò sì ṣe bí ó ti wù ú. Lẹ́yìn ìgbà tí ó bá fi ara hàn tán, ìjọba rẹ̀ yóò fọ́, yóò sì pín sí mẹ́rin ní orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé, ìjọba náà kò sì ṣọ́wọ́ àwọn ìran rẹ̀ tàbí kí ó ní agbára tí ó ń lò tẹ́lẹ̀, nítorí, a ó fa ìjọba rẹ̀ tu a ó sì fi fún àwọn mìíràn. “Ọba ìhà gúúsù yóò di alágbára ṣùgbọ́n ọ̀kan lára àwọn aláṣẹ rẹ̀ yóò di alágbára jù ú lọ, yóò sì ṣe àkóso ìjọba rẹ̀ pẹ̀lú agbára ńlá. Lẹ́yìn ọdún púpọ̀ wọn yóò dá májẹ̀mú àlàáfíà, ọmọbìnrin ọba gúúsù yóò lọ sí ọ̀dọ̀ ọba àríwá láti bá a dá májẹ̀mú àlàáfíà, ṣùgbọ́n òun kì yóò lè di agbára apá a rẹ̀ mú, bẹ́ẹ̀ ni òun kì yóò lè dádúró, ṣùgbọ́n a ó tẹrí i rẹ̀ ba àti àwọn tí ó mú un wá, àti ọmọ tí ó bí, àti ẹni tí ó ń mu lọ́kàn le ní gbogbo àkókò wọ̀nyí. “Ọ̀kan lára àwọn ìdílé e rẹ̀, ọmọbìnrin ọba gúúsù yóò dìde láti gba ipò o rẹ̀. Yóò sì kọlu ogun ọba àríwá, yóò sì wó odi alágbára; yóò bá wọn jà yóò sì borí. Yóò gba òrìṣà wọn, ère dídá àti ohun èlò oníye lórí ti fàdákà àti ti wúrà, yóò sì kó wọn lọ sí Ejibiti. Fún ọdún díẹ̀ yóò fi ọba àríwá lọ́rùn sílẹ̀. Nígbà náà, ni ọba àríwá yóò gbógun ti ilẹ̀ ọba, gúúsù, ṣùgbọ́n yóò padà sí Orílẹ̀-èdè, òun fúnra rẹ̀. Àwọn ọmọ rẹ̀ yóò múra ogun wọn yóò kó ogun ńlá jọ, èyí tí a ó gbá lọ bí àgbàrá omi ńlá, yóò sì gbá a lọ títí dé ìlú olódi rẹ̀. “Nígbà náà ni ọba gúúsù yóò jáde pẹ̀lú ìbínú, yóò sì bá ọba àríwá jà, ẹni tí yóò kó ọmọ-ogun púpọ̀ jọ, ṣùgbọ́n ọba gúúsù yóò borí i wọn. Nígbà tí a bá kó ogun náà lọ, ọba gúúsù yóò kún fún agbára, yóò sì pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún ní ìpakúpa síbẹ̀ kì yóò ṣẹ́gun. Nítorí ọba àríwá yóò lọ kó ogun mìíràn jọ, tí ó pọ̀ ju ti àkọ́kọ́ lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, yóò jáde pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun tí ó ti dira ogun fún dáradára. “Ní àkókò ìgbà náà, ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò dìde sí ọba gúúsù. Àwọn ọlọ̀tẹ̀ nínú àwọn ènìyàn an rẹ̀ yóò ṣọ̀tẹ̀ ní ìmúṣẹ ìran náà, ṣùgbọ́n wọn kì yóò borí. Nígbà náà ni ọba àríwá yóò wá yóò sì gbé ogun tì í, yóò sì kó ìlú olódi. Ogun ọba gúúsù kò ní ní agbára láti kọjú ìjà sí i; bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọ̀wọ́ ogun tó dára jù kò ní ní agbára láti dúró. Ẹni tí ó gbóguntì í yóò máa ṣe bí ó ti wù ú, kò sì ṣí ẹni tí yóò le è dojúkọ ọ́. Yóò sì fún ara rẹ̀ ní ibùjókòó ní ilẹ̀ tí ó dára, yóò sì ní agbára láti bà á jẹ́. Yóò pinnu láti wá pẹ̀lú agbára ìjọba rẹ̀, yóò sì ní májẹ̀mú àlàáfíà pẹ̀lú ọba gúúsù yóò sì fi ọmọbìnrin rẹ̀ fún un láti fẹ́ ẹ ní ìyàwó nítorí kí ó lè gba ìjọba, ṣùgbọ́n ète rẹ̀ yìí kì yóò dúró tàbí ṣe ìrànlọ́wọ́ fún un. Nígbà náà ni yóò yí ara padà sí ilẹ̀ etí Òkun, yóò mú ọ̀pọ̀lọpọ̀, ṣùgbọ́n aláṣẹ kan yóò mú òpin bá àfojúdi rẹ̀, yóò sì yí àfojúdi rẹ̀ padà sí orí rẹ̀. Lẹ́yìn èyí, yóò sì yí padà sí ìlú olódi ti orílẹ̀-èdè òun fúnra rẹ̀, ṣùgbọ́n yóò kọsẹ̀ yóò sì ṣubú, a kì yóò sì rí i mọ́. “Arọ́pò rẹ̀ yóò rán agbowó orí kan jáde láti fi ìdí ipò ọlá ọba múlẹ̀ ṣùgbọ́n ní ìwọ̀n ọdún díẹ̀, a ó pa á run, kì yóò jẹ́ nípa ìbínú tàbí nínú ogun.