Àti ẹ̀yin, ẹni tí ó ti kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín àti àìkọlà ará yín, mo ní, ẹ̀yin ni ó sì ti sọ di ààyè pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ó sì ti dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín; Ó sì ti pa ìwé májẹ̀mú nì rẹ́, tí ó lòdì sí wa, tí a kọ nínú òfin, èyí tí o lòdì sí wa: òun ni ó sì ti mú kúrò lójú ọ̀nà, ó sì kàn án mọ àgbélébùú. Ó sì ti gba agbára kúrò lọ́wọ́ àwọn ìjọba ẹ̀mí búburú àti àwọn alágbára gbogbo, ó sì ti dójútì wọn ní gbangba, bí ó ti ń yọ̀ fún ìṣẹ́gun lórí wọn.
Nítorí náà ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣe ìdájọ́ yín ní ti jíjẹ, tàbí ní ti mímu, tàbí ní ti ọjọ́ àsè, tàbí oṣù tuntun, àti ọjọ́ ìsinmi: Àwọn tí í ṣe òjìji ohun tí ń bọ̀; ṣùgbọ́n ní ti òtítọ́, nínú Kristi ni àti mu wọn ṣẹ. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tí ó ní inú dídùn nínú ìrẹ̀lẹ̀ èké àti bíbọ àwọn angẹli lọ́ èrè yín gbà lọ́wọ́ yín, ẹni tí ń dúró lórí nǹkan wọ̀n-ọn-nì tí ó ti rí, tí ó ń ṣe féfé asán nípa èrò ti ọkàn ara rẹ̀. Wọn ti sọ ìdàpọ̀ wọn pẹ̀lú ẹni tí i ṣe orí nu, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí a ń ti ipa oríkèé àti iṣan pèsè fún gbogbo ara, ti a sì ń so ó ṣọ̀kan pọ̀, tí ó sì ń dàgbà nípa ìmísí Ọlọ́run.
Bí ẹ̀yin bá ti kú pẹ̀lú Kristi si àwọn agbára ìlànà ayé yìí, kín ló dé tí ẹ̀yin ń tẹríba fún òfin bí ẹni pé ẹ̀yin wà nínú ayé, Má ṣe dìímú, má ṣe tọ́ ọ wò, má ṣe fi ọwọ́ bà á, Gbogbo èyí tí yóò ti ipa lílo run, gẹ́gẹ́ bí òfin àti ẹ̀kọ́ ènìyàn? Àwọn nǹkan tí ó ní àfarawé ọgbọ́n nítòótọ́, nípasẹ̀ àdábọwọ́ ìsìn, àti ìrẹ̀lẹ̀, àti ìpọ́nra-ẹni-lójú, ṣùgbọ́n tí kò ni èrè láti di ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara ku.